Queen's College: Ohùn tó yẹ kí ẹ mọ nípa akọni Efunjoke Coker

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi Onirese ko ba fingba mọ, eleyi to ti fin silẹ ko ni parun layelaye.

Bayii ni ọrọ ri nigba ti a ba n woye itan olukọ agba ileewe girama awọn obinrin to wa nilu Eko nii, Queens College.

Iyaafin Efunjoke Coker ni olukọ agba akọkọ ileewe naa to jẹ ọmọ bibi Naijiria, koda ni ile ẹkọ naa ni oun gan an alara ti pari ẹkọ ki o to wa pada sibẹ lati dari ẹkọ.

Ọpọ awọn akẹkọọ lo sọrọ lori akọni obinrin yii.

Awọn ti wọn ti ni anfaani lati kẹkọọ jade labẹ akoso abiyamọ yi, ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii abiyamọ tootọ to mu iṣẹ olukọ lọkunkundun pupọ.

Wọn ni alakitiyan ni Mama Coker jẹ ti kii si fi ọrọ awọn ọmọbinrin ti wọn wa labẹ rẹ ṣere.

Lọdun 1979 ni ijọba Naijiria ṣafihan imoore iṣẹ ti Efunjoke Coker ṣe ati ipa to ko lori awọn akẹkọọ ileewe naa.

Wọn fi ami ẹyẹ Member of the Order of the Federal Republic (MFR ) da a lọla ti a si tun gbọ pe o gba oye to gaju lọ nibi ayẹyẹ idanimọ 2016 KARIS award.

Gẹgẹ bi ọrọ ti aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọjade ileewe Queens College, Dokita Funmi Ajose sọ,''awokọṣe rere ni iya Coker jẹ si awọn akẹk rẹ ti eyi si lapa ni igbesi aye wọn atiiṣẹ ti wọn yan laayo''

Lẹyin ti Efunjoke Coker fẹyinti nibi iṣẹ, o jẹ ọkan lara awọn Igbimọ alaṣẹ fasiti Ibadan ati ile iwe gbogboniṣe Yolanda Polythecnic.

Bakan naa lo ti ṣe aarẹ ajọ alagbelebu pupa, Red Cross fun ọpọlọpọ ọdun.