You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osinbajo: Àwọn àwòrán bí mó ṣe ń bá Buhari sọ̀rọ̀ ni wọ́n rí bíi pé inú ń bí mi
Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Ọsinbajo ti sọrọ lori agbara ti awọn akọroyin ni lawujọ ati pataki wọn.
Bakan naa lo mẹnuba awọn aleebu to wa ninu abọ iroyin tawọn akọroyin n jẹ fun araalu lawọn oju opo ikansira ẹni lori ayelujara ati lawọn ileesẹ iroyin abalaye gbogbo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Osinbajo woye ọrọ yii nibi apejẹ alẹ kan ti wọn seto fun ikọ awọn olori lleesẹ iroyin to wa nile ijọba eyi to fi soju opo Twitter rẹ.
Nibẹ si ni Osinbajo ti salaye pe "ti mo ba ni ki n sọ tootọ, ọpọ awada tawọn eeyan maa n se lati 'sun' emi ati Buhari laaye lawọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye, lo maa n pa mi lẹrin, ti mo si maa n ri wọn bii agbekalẹ isẹ ọpọlọ to pani lẹrin pupọ."
Igbakeji aarẹ ni fun apẹẹrẹ, o dabi pe gbogbo aworan ti oun ba ti n ba aarẹ Buhari sọrọ ni wọn maa n woye bii ẹni pe oun ni ikunsinu tabi pe inu n bi oun.
Bakan naa lo tun niran iroyin eke kan ti wọn gbe jade nipa rẹ lori ayelujara eyi to ni o ti kọwe fipo silẹ nigba ti idibo aarẹ ku ọjọ diẹ.
"Ẹgbọn mi obinrin pe mi ni osu Keji ọdun ka to dibo aarẹ pe, to si n beere pe se lootọ ni mo ti kọwe fipo silẹ bii igbakeji aarẹ. Mo sọ fun wọn pe rara, ti ko si gba mi gbọ nitori pe o ti ka iroyin naa loju opo Whatsapp. Ẹ ri pe awọn awọn ileesẹ iroyin lagbara, koda, itakun agbaye lagbara pupọ ju."
Amọ sa, o ni oun nigbagbọ pupọ ninu ominira fawọn akọroyin, boya awọn akọroyin to mọ isẹ wọn nisẹ ni abi awọn to n fi isẹ wọn jataa.
- Ọkọ lu ìyàwó ọlọ́mọ mẹ́jọ pa tórí ó kọ̀ láti fún ọmọ l‘ọ́mú
- Àrà méèrírí! Ọkùnrin tí kò ríran kan rèé tó ń lọ ẹ̀rọ ata
- Ká má parọ́, ojora mú mi lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ ìbò ààrẹ - Buhari jẹ́wọ́
- Ikọ̀ ‘Àmọ̀tẹ́kùn’ dé, tí yóò dẹ́kun ààbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá - Akeredolu
- Mo kọ̀ láti ṣe àpèjẹ 'Reception' lẹ́yìn ìgbéyàwó mi nítorí...
Osinbajo fikun pe "Mo dupẹ pupọ fun atilẹyin ti a ri gba lojoojumọ, fun iroyin rere ati buburu, boya ẹ kọ iroyin daadaa abi o ku diẹ kaa to, alabasisẹpọ la jẹ si ara wa, ọrẹ si laa maa se.