Eid-el Kabir: Aisha Buhari lọ Hajj pẹ̀lú ìyàwó Ààrẹ Niger, Senegal, Gambia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ Muhammadu Buhari ti de si ilu rẹ ni Daura lati lo se ọdun Sallah, ti a mọ si ọdun Ileya, lẹyin ti o kuro ni ilu Abuja ni Ọjọ Kẹsan, Osu yii.

Aago marun un irọlẹ ni ọkọ ofurufu aarẹ balẹ ni papakọ ofurufu Malam Umar Musa Yar'adua ni ipinlẹ Katsina.

Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari ati igbakeji rẹ, Alhaji Mannir Yakubu pẹlu awọn to wa ki aarẹ kaabọ si ile ni papakọ ofurufu ipinlẹ naa.

Ọjọ kejidinlogun, Osu yii ni aarẹ yoo pade si ile aarẹ ni ilu Abuja saaju iburawọle fun awọn minisita tuntun ti wọn sẹsẹ yan.

Bakan naa ni iyawo aarẹ Buhari, Aisha Buhari fi si oju ikansiraẹni Instagram rẹ pe oun wa ni Mina pẹlu awọn iyawo aarẹ orilẹede miran ni Afirika lati lọ se Hajj.

Aisha wa gbadura fun alaafia ati itẹsiwaju fun awọn orilẹede lagbaye.