Howards Graduates: Barrack Obama gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde nímọ̀ràn láti fi àwọ̀ wọn yangàn

Yoruba ni bi eegun ni ba jo re, ori a maa ya atọkun rẹ, bẹẹ si ni inu ẹni kii dun, ka pa mọra.

Bẹẹ lọrọ ri ni fasiti Howard to wa lorilẹede Amẹrika, nigba ti awọn ọmọ Naijiria fakọyọ julọ laarin awọn akẹkọjade to n kuro nile ẹkọ fasiti naa.

Ileẹkọ fasiti Howard lo ko akẹkọjade mẹrindinlọgọrun silẹ, ti mẹrindinlaadọta ninu wọn si jẹ ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn alejo to wa nibi ayẹyẹ ikẹkọjade ileẹkọ naa, ti wọn si la ẹnu silẹ, lai lee pa de, nigba ti akẹkọjade ti wọn jẹ ọmọ Naijiria, gba ami ẹyẹ mẹrindinlogun ninu ami ẹyẹ mẹtadinlọgbọn ti fasiti naa ko silẹ fawọn akẹkọ ti ọpọlọ wọn jipepe julọ.

Iroyin naa ni iru isẹlẹ bayii ko tii waye ri ni ile ẹkọ fasiti Howard tabi ni ile ẹkọ fasiti kankan ni orilẹede Amẹrika, awọn ọmọ Nigeria yii si ni oju gbogbo n wo nibi ayẹyẹ naa pẹlu itan ara ọtọ ti wọn fi lelẹ yii.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ikẹkọjade naa gẹgẹ bii alejo pataki, aarẹ tẹlẹ ni orilẹede Amẹrika, Barrack Obama, ti oun naa jẹ adulawọ, lo sọrọ nipa ẹlẹyamẹya, to si rọ awọn akẹkọjade ileẹkọ naa lati maa fi awọ wọn yangan, ki wọn si nifẹ bi Ọlọrun se da wọn.

Obama ni, pẹlu iriri oun lasiko ti oun wa nipo aarẹ, oun gba pe lootọ ni iwa ẹlẹyamẹya wa, to si wọpọ ni orilẹede naa, amọ o ni ilẹ naa si lee ni agbega siwaju si, tawọn oniruuru ẹya ba gbagbọ ninu ẹya wọn, ti wọn ko si gba kamu.