Imo: Aléjò mẹ́wàá ṣòfò ẹmí níbi ayẹyẹ ìgbéyawó

Ìjàmba ṣẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Imo lọ́jọ́ ajé lẹ́yìn ti alejò mẹ́wàá jẹ ọlọ́run nípe nípasẹ̀ èèfi ẹrọ amúna wá níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ìlànà ìbílẹ̀.

Yàtọ̀ sí èyí, ènìyàn bii ọgbọ̀n ló wá ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀rún ni onírúurú ilé ìwòsàn ní ìjọba ìbílẹ̀ Ikeduru àti Mbatoli ìpínlẹ̀ náà báyìí nítori wọ́n fa èèfi ẹ̀rọ amúna wá símú.

Ìròyìn sọ pé Favour àti Ifeanyi ṣe ìgbéyàwó ìlànà ìbílẹ̀ ní agbolé Uzoegbu Umuomumu Mbieri ní ìjọba ìbílẹ̀ Mbatoli ní ọjọ́ àìkú, ìjàmbá ọ̀hún ṣẹ̀ lẹ́yìn ti ọkọ àti ìyàwó parí gbogbo ètò tí wọn sí kúrò ṣùgbọ́n ti àwọn ẹbi tí ọ̀nà wọ́n jìn pinu láti dúro sùn ní agbolé náà.

Lásìkò tí Ezuruke tó jẹ́ olóri ìlú náà ń ṣàlàyè ìṣẹ̀lẹ̀ abúrú ọ̀hún o ní ó hàn gbangba pé èèfí gẹnẹretọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ títí di ààrọ ọjọ ajé ní nígbà ti wọ́n fi tipátipá ṣí ìlẹ̀kùn, àwọn kan ti jẹ́ ọlọrun nípè.

"Mo mọ̀ pé kí ṣe ọ̀rọ̀ májèlé oúnjẹ, bíkò ṣe èèfi gẹnẹrátọ̀ ló pá wọ́n , èèfi náà ń kì mọ́ èèyàn láyà, àwọn obi ìyawó wà láàyé sùgbọ́n enìkeji tó jẹ ìbejì fún ìyàwó àti àwọn abúrò rẹ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Imo Rabiu Ladodo tó fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ṣàlàyé pé àwọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní pẹrẹwu lóri ọ̀rọ̀ náà.

Ladodo ní " ẹ̀rọ amúná wá náà sì wà ní títàn sílẹ̀ nínú yàrá ìdána títí ilẹ̀ fi mọ tí ilẹkun àti fèrèsé ti àwọn alejo sùn si wà ni títì pa.