Democracy Day: Àkójọpọ̀ àwòrán láti ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ogun àti Kwara fún ìbúra gómìnà tuntun
Ẹ wo awọn aworan igbaradi fun iburawole ni awọn ipinlẹ:
Ipinlẹ Ọyọ:
N jẹ ẹ mọ pe gomina ti yoo se ibura lọjọru ni ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti kan si papa iṣere Obafemi Awolowo nibi ti ayẹyẹ ibura naa yoo ti waye.
Lasiko to si wa ni ibudo naa, lo se idanilẹkọ nipa bi eto igbaradi naa yoo se waye. Koda, o tun wọ inu ọkọ ti yoo gbe kaakiri wo .
Koda, Awọn ase ibudo lọṣọ atawọn ohun eelo ikọrin gan ti wa nikalẹ fun ayẹyẹ ibura naa.







Ipinlẹ́ Ogun:
Gbogbo eto lo ti to bayii ni papa isere idaraya MKO Abiola nilu Abẹokuta fun ayẹyẹ ibura gomina ti ilu dibo yan ni ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun.
Akọroyin BBC Yoruba to ti balẹ silu Abẹokuta fi awọn aworan ransẹ nipa ibi ti igbaradi naa de duro.




Ipinlẹ Kwara:
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ipinlẹ kan ko mu ayẹyẹ ibura awọn gomina tuntun ni kekere, ti wọn si fẹ ṣe ayẹyẹ ibura naa tilu-tifọn, amọ eyi ko ri bẹẹ rara ni ipinlẹ Kwara.
Idi ni pe wọọrọwọ ni wọn fẹ se ibura gomina ti ilu dibo yan, Abdulrahman Abdulrazak ti ipinlẹ Kwara, ti ayẹyẹ naa ko si ni kọja ile ijọba ipinlẹ naa.
Akọroyin BBC Yoruba to ti kalẹ silu Ilọrin fi ye wa pe, ko si pọpọsinsin kankan to n waye nipa ibura naa.


Akojọpọ aworan naa wa lati BBC












