Zainab Aliyu: A kò mọ́ pé wọ́n kẹ́ òògùn olóró sí àbúrò mi l'ọ́rùn- Hajara

Àkọlé fídíò, A kò mọ́ pé wọ́n kẹ́ òògùn olóró sí àbúrò mi l'ọ́rùn

Lẹyin ti iroyin jade pe wọn ti fi Zainab Aliyu si ẹwọn ni Saudi Arabia, ni awọn kan bẹ̀rẹ̀ iwọde ati ipolongo pe ki wọn o tu u silẹ.

Ipolongo naa de ori ẹrọ ayelujara.

Ọgbọnjọ oṣu Kẹrin ni o gba ominira kuro ni ẹwọn lẹyin ti ijọba Naijiria da si ọ̀rọ̀ naa.