You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Soyinka: Háà, ó ṣe. Ìran mi já Nàìjíríà kulẹ̀
Onimọ nipa iwe kikọ ati Litiresọ, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti sọ pe, iran oun ti ja orilẹede Naijiria kulẹ patapata.
Lasiko to n sọrọ lori eto ileeṣẹ BBC kan, Hard Talk, Soyinka ṣalaye wipe, afojusun ati ala ti iran oun ni fun orilẹede yii ko ti i wa si imuṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu ọrọ rẹ, Soyinka ni ''mo fi oni we igba ti a n d'agba, ti ọpọlọpọ wa lọ kawe nilẹ okeere, nigba ti gbogbo wa sare pada sile lẹyin ti a kẹkọọ nilẹ okeere.
A ri ara a wa gẹgẹ bi iran tuntun ti yoo gbe ilẹ Africa de ipo ti yoo 'se itẹwọgba loju gbogbo aye, ti yoo si le figa-gbaga pẹlu ẹnikẹni, ṣugbọn eyi ko ti ṣẹlẹ.''
Lori ọrọ eto idibo gbogboogbo to kọja, Soyinka sọ pe eto idibo ọdun 2019 jẹ ọkan lara awọn idibo to ti i bani lọkan jẹ julọ ni Naijiria.
'Fun emi gẹgẹ bi ẹnikan, ko ṣeesẹ fun mi lati yan ẹnikan laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Atiku Abubakar - awọn mejeeji lo ni ìtàn to n tọ wọn lẹyin, eyi to mu ki eeyan wa ọna abayọ mi.