WAEC Result: Olùdíje kò nílò ìwé ẹ̀rí WAEC fún ìpò ààrẹ tàbí gómìnà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oludari ipolongo ibo aarẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, amofin agba Festus Keyamo ni oludije ko nilo iwe ẹri WAEC lati dije fun ipo aarẹ tabi gomina lorilẹede Naijiria.

Keyamo to fọrọ naa lede loju opo Twitter ṣalaye pe awọn nnkan miiran wa to jẹ amuyẹ fun awọn oludije fun ipo gomina tabi aarẹ gẹgẹ bi akọsilẹ iwe ofin orilẹede Naijiria.

Keyamo ni koda ti oludije ba ti di ipo oṣelu mu fun igba pipẹ, ko nilo iwe ẹri girama mọ lati dije fun ipo kan tabi omiran.

Ọrọ yii jẹ esi Keyamo si ọrọ to jẹyọ ninu eto kan lori ẹrọ amohunmaworan niluu Eko lọjọ Aiku nibi ti ẹgbẹ oṣelu ti sọ pe Aarẹ Buhari ko koju oṣuwọn lati jẹ aarẹ nitori awuyewuye to wa lori iwe ẹri WAEC rẹ.

Keyamo fi ọrọ oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oṣun Ademola Adeleke ṣe apẹrẹ pe wọn gbe e lọ sile ẹjọ lori iwe ẹri WAEC bakan naa.

Amofin agba Keyamo ṣalaye pe ẹsẹ 318 ninu iwe ofin Naijiria sọ pe oludije gbọdọ ni iwe ẹri girama tabi eleyi to dabi rẹ, bakan naa o gbọdọ mọ ede oyinbo kọ ko si mọ ọ ka.

Keyamo ni ajọ WAEC ti jẹri si i pe Aarẹ Buhari ni iwe ẹri girama, ṣugbọn o ni ọrọ ko ri bẹẹ pẹlu Adeleke l'Oṣun.

Keyamo ni iwe ẹri ile iwe alakọbẹrẹ ni iwe ofin Naijiria sọ pe o tun dabi iwe ẹri girama.

O ni eleyi ti ko le jẹ itẹwọgba ni bi oludije ba ṣe ayederu iwe ẹri lati dije fun ipo oṣelu.