You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Cyclone Idai: Ààrẹ Mozambique ní òun rí ọ̀pọ̀ òkú tó lé téńté lórí odò
O kere tan o le ni eeyan ẹgbẹrun kan ti ẹmi wọn ti bọ ninu ọwọja afẹfẹ iji lile, ti wọn pe ni ‘Cylone Idai’, to bẹ silẹ ni orilẹede Mozambique.
Gẹgẹ bi aarẹ Filipe Nyusi ti salaye, oun ri ọpọ oku eeyan ti wọn le tente loju oniruuru odo lasiko ti oun foninu baalu rin kaakiri orilẹede naa.
Osisẹ alaanu kan labẹ ajọ isọkan agbaye sọ fun BBC pe gbogbo ile to wa nilu Beira, ti apapọ awn eeyan to to idaji miliọnu n gbe, lo bajẹ patapata.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gerald Bourke, latinu aj to n risi ipese ounjẹ labẹ ajọ isọkan agbaye ni "Ko si ile ti afẹfẹ lile naa ko fi ọwọ ba. Ko si ina ọba, ko si ẹrọ ibaraẹnisọrọ, bẹẹ si ni awọn oju popo kun fun opo ina ati waya ina ọba to ja silẹ."
Awọn osisẹ alaanu yii lo gbogbo oru lati gbe awọn eeyan sọkalẹ lati ori igi. ti iji lile naa si ti ran eeyan to le ni ọgọsan si ọrun ọsan gangan, ni ẹkun guusu Afrika.
Ẹgbẹ alagbelebu pupa lagbaye si ti se apejuwe isẹlẹ ajalu yii gẹgẹ bii eyi to lagbara julọ, to si ba ni lẹru.
Koda gbogbo oju ọna to so ilu Beira papọ mọ awujọ agbaye lo ti bajẹ patapata, sugbọn eto irinna ofurufu ti bẹrẹ pada.