You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Emeka Ihedioha: Ibo 273,404 lo ni, ti Nwosu to tẹle si ni ibo 190,364.
Ajọ eleto idibo INEC ti kede Igbakeji olori Ile Igbimọ Aṣoju-ṣofin nigba kan ri, Emeka Ihedioha to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP gẹ́gẹ́ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina Ipinlẹ Imo.
Ẹni to gbe ipo keji ni Uche Nwosu ti ẹgbẹ oṣelu AA, iyẹn àna gomina ipinlẹ naa Rochas Okorocha. Ibo naa fa awuyewuye to pọ ti awọn eniyan si bẹnu atẹ lu bi Okorocha ṣe fa àna rẹ kalẹ lati rọpo rẹ.
Ihedioha ni ibo 273,404 ti Nwosu si ni ibo 190,364.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
Oludije ẹgbẹ oṣelu APGA, Ifeanyi Ararume ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 114, 676 ti Hope Uzondima ti ẹgbẹ oṣelu APC si ṣe ipo kẹrin, pẹlu ibo 96,458.
Gomina Imo tẹlẹ ri, Ikedi Ohakim lo gbe ipo karun-un pẹlu ibo 6,846.
Ki wọn to ṣe ikede naa, rogbodiyan fẹ bẹ silẹ ni ipinlẹ naa, bi awọn ọmọ ẹgbẹ AA ati PDP ṣe n leri wipe, awọn yoo da wahala silẹ ti oludije awọn ko ba bori.
Nitori naa ni INEC ṣe kọkọ da ikede naa duro.