You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ethiopian Airlines crash: Èèyàn 157 dèrò ọ̀run nínú bàálú tó já
Bayii, apero ajọ iṣọkan agbaye to yẹ kó bẹ̀rẹ̀ loni ti mọ iṣẹlẹ ijamba yii lára pupọ.
Kete ti wọn ṣide ipade ẹka ijiroro lori ọrọ awujọ oni lajọ iṣọkan agbaye ni Nairobi ni wọn ti dide iṣẹju kan fun gbogbo oloogbe inu iṣẹlẹ ijamba ọhun.
Ajọ UN ṣalaye fun BBC pé awọn eniyan wọn naa wa ninu iṣẹlẹ ibi naa to dùn wón gidigidi.
Iroyin fihan e ọmọ Naijiria meji wa lara awọn to ku ninu baalu orilẹ-ede Ethiopia kan, Boeing 737 to ja lulẹ loju ọna rẹ lati Addis Ababa si Nairobi.
Ojogbon Abiodun Bashua to jẹ oṣiṣẹ fẹyinti aṣoju Naijiria ni Sudan ati ọjọgbọn Pius Adesanmi to jẹ olukọ agba lori aṣa ilẹ Adulawọ ni fasiti ni Canada.
Baalu naa ko eero mọkandinlaadọjọ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ baalu mẹjọ. Awọn alaṣẹ ileeṣẹ baalu naa ni iṣeju mẹta pere ti baalu naa gbera ni o ja lulẹ
Awọn orilẹede mẹtalelọgbọn ti awọn eniyan wọn ku nibẹ ree:
Kenya (32), Canada (18), Ethiopian (9), China (8), Italy (8), American (8), French (7), British (7), Egypt (6), Netherlands (5), UN passport (5), India (4), Russia (3), Morocco (23), Israel (2), Belgium (1), Uganda (1), Yemen (1), Sudan (1), Togo (1), Mozambique (1), Norway (1), Nigeria (1)
Awọn oṣiṣẹ aranilọwọ ti ijọ aguda mẹrin naa wa ninu ijamba naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa sọ pe ijamba naa waye ni nkan bi aago mẹsan ku iṣẹju mẹrindinlogun lowurọ ọjọ Aiku, laipẹ to kuro ni olu ilu oeillede Thiopia.
Aago meje aabọ (GMT) ni ọkọ ofururu naa yẹ ko balẹ si papa'kọ ofurufu Jomo Kenyatta to wa ni Kenya.
Akọroyin BBC kan ba arakunrin kan ti iṣlẹ naa ṣoju rẹ Bekele Gutema to wa ni agbegbe naa nigba sọ wipe:
''Ibugbamu to lagbara kan ni a gbọ ti ina si sọ, o pọ to bẹẹ ti a ko le sun mọ ibẹ. Gbogbo nkan to wa nibẹ lo ju run. Awọn panapana de ibẹ ni bi i wakati mẹta lẹyin ti ọkọ naa ja lulẹ. Ko si ẹnikan kan to le yè."
Olootu orilẹ-ede naa, Abiy Ahmed fi sori Twitter pe ''oun ba awọn mọlẹbi to padanu eniyan wọn kẹdun iku awọn to ku sinu ijamba naa.''
Awọn ọmọ Naijiria to tun wọ ọkọ to ja lulẹ naa ri ti n fi ibanujẹ wọn han lori iṣẹlẹ naa. Ọkan ninu wọn ni Ọjọgbọn Joe Abah.