BBC Yorùbá: Ọ̀pọ̀ òjò ti rọ̀, ilẹ̀ ti fimu láàrin ọdún kan BBC Yorùbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni aarin ọdun kan ti BBC News Yoruba ti bọ sori afẹfẹ, oniruuru iroyin manigbagbe ni o ti gbe sita eleyi ti o ti rinlẹ kọja orilẹede Naijiria.

Bi a ti ṣe n mu iroyin ijinlẹ pẹlu iwaadi ti ko lẹjanbakan ninu wa, lawọn ọdọ naa n gba ẹtọ tiwọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbogbo aṣa ati iṣe Yoruba ni a n ṣi aṣọ lawọn oju opo rẹ fun igbadun ati idanilẹkọ fawọn eeyan kaakiri.

Diẹ lara awọn iroyin manigbagbe to waye laarin ọdun kan naa niwọnyii:

Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ọjọgbọn Wọle Soyinka

Ọkan pataki lara awọn iroyin to waye ni ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu agba ọjọgbọn, Wọle Soyinka, nibi to ti pariwo pe "Ti mo ba dara pọ m'ẹgbẹ Ọbasanjọ, wọn gbọdọ yẹ mi lọpọlọ wo"

Iroyin yii di itẹwọgba kaakiri agbaye bi ọmọ tuntun. O si wa lara awọn akọṣe iṣẹ BBC News Yoruba ti o fọn rere rẹ kari aye.

Tunde Bakare: Ọlọrun kìí yan ọ̀lẹ sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rárá

Eyi ni ifọrọwanilẹnuwo pẹlu gbajugbaja pasitọ Tunde Bakare lasiko ti ọrọ idamẹwa sisan n fa ariyanjiyan lorilẹede Naijiria.

Bi BBC News Yoruba ṣe fọrọ wa Daddy Freeze, to n lewaju igun to ni pe idamẹwa ko lẹtọ, lasiko naa ni o tun ba Pasitọ Bakare sọrọ pẹlu nigba naa.

Kádàrá ní ọ̀rọ̀ ẹ̀dá láyé, Mo gbà pé Ọlọrun ló kọ ikú ọkọ mi ni Saudi

Eyi ni itan Obinrin kan ti o di alabọ ara nitori ijamba ọkọ to waye ni ilẹ Saudi, ninu eyi ti ọkọ rẹ, Dokita Ajani Raji ti di oloogbe.

Okiki iroyin yii kan to bẹẹ gẹẹ, ti awọn akanda ẹda lawujọ pẹlu fi gba pe BBC News Yoruba jẹ ohun wọn, lati fi sọ ẹdun ọkan ti wọn naa faraye.

'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'

Ṣe ẹ ranti ọdun ijẹṣu ni ilu Ilaramọkin, nibi ti awọn ọdọ ti n yọ pankẹrẹ ati atori si ara wọn lati fi sami ajọyọ ọdun ijẹṣu nibẹ. Bi wọn ṣe n ṣe, BBC news Yoruba naa wa nibẹ.

Ayefẹlẹ: Orí ìkúnlẹ̀ ni ìyàwó mi wà, tó ń bẹ gómìnà, láti 11pm si 4am

Nigba ti wahala wiwo ile iṣẹ redio gbajugbaja akọrin ni, Yinka Ayefẹlẹ waye ni Ibadan, BBC News Yoruba lo lewaju iroyin ohun gbogbo to n lọ nigba naa, lai jẹ ki eti araalu di si bi ọrọ naa ṣe lọ.

Ko rọrun, ṣugbọn nitori pe ilepa ileeṣẹ BBC News Yoruba ni lati rii pe gbogbo eeyan lawujọ lo lanfani ati sọ ẹdun ọkan wọn, a ko tẹti

Ekiti Election: Ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin nàirà ni ẹnikọ̀ọ̀kan ń gbà

Nigba ti eto idibo ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun waye, lati ibẹrẹ de opin ni ileeṣẹ BBC News Yoruba ti gbe iroyin mejeeji yi lai fi ohunkohun pamọ fun araalu.

Koda, aṣa " Dibo koo sebẹ" to di gbajugbaja ọrọ lawujọ oṣelu Naijiria bayii, ko ṣẹyin BBC NEWS Yoruba, nitori awa gan an lara.

Nipasẹ iṣẹ iwaadi iroyin to rinlẹ ni BBC News Yoruba fi ṣawari ibudo ti wọn ti n fi ẹgbẹrun mẹrin naira ra ibo ni ilu Ado Ekiti.

Osun Election Results 2018: Ademola Adeleke ní wọ́n jà òun lólè

Ṣe ẹ ranti Sẹneto onijo, iyẹn Sẹnetọ Ademọla Adeleke?

BBC ni ileeṣẹ iroyin akọkọ ti o kọkọ ba Adeleke sọrọ, lẹyin ti ọrọ idibo rẹ ipinlẹ Ọṣun ri bo ṣe ri fun un.

Ko si si idi meji fun eyi ju igbẹkẹle ati igbagbọ ti o ni ninu ileeṣẹ BBC News Yoruba gẹgẹ bii ikanni ti ko ni fi igba kan bọ ọkan ninu.

#67yearoldmother: Ọ̀pọ̀ gbà pé àdúrà ló gbà lóri tọkọtaya Otubusin

Ṣe ẹ ranti iroyin iya ọmọ ọdun mẹtadinlọgọrin to bi akọbi rẹ ni ilu Abẹokuta?

Nigba ti o ṣẹlẹ, BBC News Yoruba lo ṣaaju lati tu iṣu de isalẹ ọrọ naa.

#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi

Lori awọn aṣa to ti fẹ parun, BBC News Yoruba gbe iroyin kan jade nipa ọmọbinrin awẹlẹwa kan ti o kọ ila ati iriri rẹ lori ila naa.

Eyi si mu ipakiyesi wa fun aṣa ila kikọ ni ilẹ Yoruba ati ohun tawọn eeyan n koju nipa rẹ.

Mike Ifabunmi: Ifá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohun ti Ọlọrun kò lè ṣe

Bakan naa ni BBC News tun gbe iroyin Mike Ifabunmi, ọmọ ilẹ Brazil, ti o di ẹlẹsin ifa pẹlu Yoruba to dan mọran lẹnu rẹ.

Obasanjo: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn

Ninu ifọrọwerọ BBC News pẹlu aarẹ Naijiria nigbakan ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ẹ ri bi o ṣe lọ kaakiri agbaye.

Koda titi de awọn orilẹede bii Amẹrika, ilẹ Gẹẹsi ati Canada, ka fi mọọ nibẹ, ni wọn gba iroyin naa ti wọn si da sii pẹlu.

Ifọrọwerọ itagbangba fawọn to n dupo oṣelu ni Naijiria

Fun igba akọkọ, BBC News Yoruba ṣagbekalẹ ifojurinju laarin awọn oludije ipo oṣelu ati araalu ni ipinlẹ Oṣun ṣaaju idibo gomina nipinlẹ naa.

Eyii ni igba akọkọ ti wọn yoo fi ede abinibi ṣe ifọrọwerọ bayii lorilẹede Naijiria.

Ipinlẹ Kwara, Eko, Ọyọ ati Ogun lo tun tẹlee eyi ti o yi iha ti ọpọ kọ si eto oṣelu lorilẹede Naijiria titi de oke okun pada.