Banky W ní àjọ INEC ṣe àṣìṣe orúkọ rẹ̀ àti ti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ nínú ìwé ìdìbò 2019

Oríṣun àwòrán, Banky W/ instagram
Gbajugbaja olorin takasufe lorilẹede Naijiria, Bankọle Wellington ti ọpọ mọ si Banky W ti pariwo sita pe ajọ eleto idibo, INEC ṣi orukọ oun kọ ninu orukọ awọn oludije ti ti wọn gbe jade laipẹ yii.
Bakan naa lo ni ajọ INEC ṣi ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu oun, iyẹn, Modern Democratic Party, tẹ si ori iwe idibo ti ajọ naa fẹ lo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Banky W. gbe e jade lori ikanni instagram rẹ pe gbogbo ọna ti awọn mọ ni awọn ti gba lati rii boya wọn lee tun ami idanimọ naa tẹ ṣugbọn o dabi ẹni pe ko lee bọ sii.
"Ami idanimọ ti yoo ṣafihan ẹgbẹ oṣelu MDP lọjọ idibo kọ ni wọn tẹ. A ti gbiyanju lati mọ boya wọn lee tun iwe idibo naa tẹ ṣugbọn ko daju pe yoo ṣe e ṣe."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O ni eyi ko ni domi tutu si ọkan ẹgbẹ oṣelu naa nitori afojusun rẹ.
"Bakan naa ni wọn tun ṣi orukọọ mi kọ, ṣugbọn ko si iṣoro lori eyi nitori ko kuku ni si orukọ oludije lori iwe idibo ni ọjọ idibo."
Banky W. n dije fun ipo aṣoju-ṣofin ti yoo maa ṣoju ẹkun apapọ Eti-Osa ni ile aṣofin apapọ orilẹede Naijiria.













