2019 Elections: Níbo la bá ètò ẹ̀kọ́ dé?

Awọn oludibo ni Nigeria yoo ma a dibo sipo aarẹ ni 19 February lati yan ẹni ti wọn fẹ nitori ohun ti awọn oludije naa ti sọ.

Sugbọn bawo ni wọn yoo se mọ wi pe ohun ti wọn sọ jẹ otitọ?

Lati ibẹrẹ ọsẹ yii, BBC yoo ma a se agbeyẹwo ọrọ ti awọn oludije to gbajugbaja ti sọ lori ohun ti awọn yoo se lori eto ẹkọ, eto ilera, eto ọrọ aje ati eto aabo.

Agbeyẹwo naa yoo da lori awọn akọsilẹ to han si gbangba.

Eto ẹkọ lorilẹede Nigeria ni a o kọkọ ma a gbeyẹwo.

Atupalẹ yii yoo mu ki awọn eniyan kiyesi eto ilana oṣelu awọn oludije yatọ si ẹgbẹ oṣelu wọn.

Atupalẹ yii yoo jẹ otitọ, ti ko si ni fi si apa kan ju ti omiran lọ pẹlu akiyesi si awọn ohun ti ẹgbẹ oṣelu yii yoo ṣe fun awọn ara ilu.