Ọ̀ràngún ti Ila: Èdè àti àṣà Yorùba ní láti jọ wá lójú fún ìdàgbàsókè ìran Yorùbá

Ọrangun ti ilu Oke Ila fi tinu tinu rẹ gba awọn ọmọ Yoruba nimọran lati ma jẹ ki aṣa adayeba wọn parun.

Bi aye ṣe n yi ti aṣa naa n ba a yi pẹlu, Ọba Adedokun Abolarin sọ pe bi a ba gbe aṣa larugẹ, yoo wu ajoji ati ara ilẹ okeere lori yoo si ya wọn lara lati fẹ mọ nipa aṣa wa sii.