You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Miss Africa 2018: Àwọn nkan tó ṣẹlẹ̀ ní Miss Africa 2018, Calabar
Diẹ lo ku ki eto yiyan omidan ilẹ Afrika, ikẹta iru rẹ to waye nilu Calabar lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, 2018, di nkan mi i lẹyin ti wọn kede ẹni to jawe olubori.
Omidan Dorcas Dienda, to jẹ́ aṣoju orilẹede Congo lo jawe olubori nibi eto naa.
Ni kete ti wọn kede rẹ pe oun ni omidan tuntun fun ilẹ Afrika, to si n rin, yan fanda lori itage ni ina dede gba mọ irun ori rẹ.
Niṣe ni ina fo lati ara awọn ina igbalode ti wọn fi ma n dawọ idunnu nibi ayẹyẹ fo si i lori, ti irun rẹ si gbina.
Ṣugbọn, awọn kan lara awọn to ṣe akoso eto naa ti sọ wi pe irun agbebọ ori, wiigi, to de sori lo gbina, kii ṣe irun rẹ gan n gan.
Gomina ipinlẹ Cross River to gbelejo eto naa, Ben Ayade, sọ pe eto naa ni afojusun lati ṣafihan ẹwa ilẹ Afrika ati ohun to yẹ ki ọkunrin mọ tabi reti lati ọdọ obinrin ilẹ Afrika.
Orilẹede mẹẹdọgbọn lo kopa ninu idije naa. Congo, Sierra Leone, Ghana, Cameroon, Zambia, Burundi, South Africa, Zimbabwe, Malawi, Tunisia, Tanzania, Botswana, Angola, Uganda, Somalia, Algeria, Togo, South Sudan, Kenya, Gambia, Namibia, Rwanda, Mozambique, Morocco ati Nigeria.