You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sophie Oluwole: Màmá Onímọ̀ Òye kọjá lọ lẹ́ni ọdún 83
Awọn ọmọ kaarọ oojiire ti n kẹdun Ọjọgbọn Sophie Oluwole to dagbere fun aye ni ẹni ọdun mẹtalelọgọrin.
Sophie Oluwole ni wọn bi ni agbeegbe Igbara-Oke ni ipinlẹ Ondo ni ọdun 1936, ti o si kawe gboye lati fasiti Ile-Ifẹ ni bi ogoji odun seyin.
Akẹẹkọ gboye onimọ oye, Sophie Oluwole to tun jẹ Ọjọgbọn ninu imọ asa, ise Yoruba ati ti ilẹ Afirika lapapọ dagbere fun aye ni ọsan Ọjọ Isinmi, lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.
Gbajugbaja oniroyin, Funmi Iyanda sọ nipa igbe aye oloogbe naa to bu iyi kun imọ ilẹ adunlawo nipa oselu, idagbasoke ile Afirika ati ọrọ aje naa.
Taiwo Obe naa fikun wipe Sophie Oluwole ti awọn eniyan ma n pe ni "mamalawo" lo jẹ obinrin akọkọ to kawe gboye ọmọwe ni orilẹede Naijiria.
Ọjọgbọn Oluwole naa to kọ ọpọlọpọ akẹẹkọ ni fasiti ilu Eko, ni ọpọ eniyan mo wi pe o sa ipa rẹ fun igbelarugẹ awọn obinrin, imọ ijinlẹ Yoruba ati ti ilẹ adulawo lapaapọ.