You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
TraderMoni: Igbákejì ààrẹ Osinbajo ní owóòyá TraderMoni kìí ṣe owó ìbò rírà
Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yẹmi Oṣinbajo ti pariwo sita pe owo iranwo fawọn ọlọja ati oniṣowo ti wọn pe ni 'TraderMoni' eleyii ti ijọba apapọ n pin kaakiri awọn ọja bayii kii ṣe fun rira ibo awọn araalu.
Ọpọ awọn onwoye, paapaa awọn ẹgbẹ alatako, ni wọn ti ke ibosi sita lori owo naa pe adọgbọn fi owo tu oju awọn ọlọja ki wọn lee dibo ni.
Oṣinbajo ni igbesoke aye awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaa awọn oniṣowo kekeke, ni owo TraderMoni wa fun.
O ni awọn ọta oniṣowo ni wọn n pe owo naa ni owo raborabo.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn aṣofin apapọ buwọ lu owo naa ki ijọba apapọ to bẹrẹ pinpin rẹ kaakiri.
Igbakeji aarẹ ni owo naa kii ṣe owo ọfẹ nitoripe ẹka banki idaṣẹsilẹ, BOI kan wa ti o n mojuto nina ati gbigba pada wọle owo naa.
O ni aarẹ Buhari lo ti kọkọ bẹrẹ irufẹ eto bayii ni ilu rẹ ki o to de ipo aarẹ pẹlu ajọ kan eyi ti o n ṣeto ẹyawo alabọde fun awọn oniṣowo kerejekereje bi alakara atawọn okoowo miran.
O fi kun un pe o din diẹ ni miliọnu kan abọ eeyan ti wọn ti janfani eto owooya na.