You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Girma Wolde Giorgis: Ààrẹ Ethiopia tẹ́lẹ̀ jáde láyé lẹ́ni ọdún 94
Aarẹ orilẹ-ede Ethiopia tẹlẹ Girma Wolde Giorgis ti papoda ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun.
Giorgis jẹ Aarẹ ilẹ Ethiopia laarin ọdun 2001 si ọdun 2013.
Ẹwẹ, Olootu ijọba orilẹ-ede naa, Abiy Ahmed ti ranṣẹ ibani kẹdun si ẹbi oloogbe ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Olootu ijọba ilẹ Ethiopia ṣapejuwe Giorgis bi ẹni ti ọpọ n wo bi awokọsẹ nigba aye rẹ, bakan naa lo kede pe ijọba yoo ṣe oku rẹ gẹgẹ olori orilẹ-ede naa tẹlẹ ri.
Nigba ti Giorgis wa lori laeefa, o gbiyanju lati fopin ija ilẹ to wa laarin orilẹ-ede Ethiopia ati Eritrea to wa lẹgbẹ rẹ.
Giorgis to jẹ oniṣowo ati oṣiṣẹ ile ifowopamọ fi iyawo rẹ ati ọmọ marun un saye silẹ lọ.