You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Baba Sala: Ẹbí, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ péjú láti ṣ'ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Baba Sala nílùú Ilesa
Awọn ebi, ara, ọrẹ ati ojulumọ lo korajọpọ nilu Ileṣa lati ṣe ẹyẹ ikẹhin fun alagba Moses Ọlaiya Adejumọ ti ọpọlọpọ awọn eeyan mọ si Baba Sala.
Ọjọ keje ọṣu kẹẹwa ọdun 2018 ni Baba Sala jade laye lẹni ọdunmọkanlelọgọrin.
Isin idagbere ikẹhin n lọ lọwọ nile ijọsin ti Baba Sala ti jẹ oluṣọ aguntan, 'The Sacred Cherubim & Seraphim Church of Nigeria and Overseas Inc.' to wa nilu Ileṣa.
Lẹhin isin idagbere ni wọn yoo gbe baba Salah wọ kaa ilẹ lọni ilẹ rẹ to n bẹ ni agbegbe Abiọla Avenue nilu Ileṣa.