World Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé
Ọjọ́ Ajé òní ni ayajọ̀ ọjọ́ síse ìgbọ̀nsẹ̀ lọ́nà ìmọ́tótó òde òní.
Idi ree ti BBC Yoruba fi bọ sigboro lati mọ bi awọn eeyan se n se imọtoto ibiti wọn n se igbọnsẹ si, oniruuru ọna ti wọn n gba se igbọnsẹ ati ibi ti wọn n se igbọnsẹ si, ati lati mọ bi ayajọ ‘World Toilet Day’ ti ye wọn si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn eeyan to ba BBC Yoruba sọrọ ni, asiko ti to fawọn osisẹ wolewole lati bẹrẹ si ni lọ lati ojule de ojule, ki wọn si dẹkun asa sise igbọnsẹ sinu odo tabi oju titi, ka baa lee dena arun onigba meji.
Bakan naa ni wọn rọ ijọba lati bẹrẹ eto ilanilọyẹ fawọn araalu, ki wọn lee ni oye ohun ti ayajọ síse ìmọ́tótó ilé ìgbọ̀nsẹ̀ láwùjọ wa, wa fun.