Surety - Àwọn kan n ṣe onídùró gẹ́gẹ́ bi okòówò

Kini o gbọdọ mọ ki o to ṣe oniduro ẹnikẹni?

Iwọ ti o ba fẹ gba oniduro gbọdọ mọ ki o si ni oye irufẹ ẹsun ti wọn fi kan ẹni to fẹ ṣe oniduro fun.

O lewu fun ọ ti o ko ba mọ ẹsun ti wọn fi kan ẹni to n jẹjọ.

Ti ẹni naa ba sa lọ, ori rẹ ni gbogbo atunbọtan ẹjọ yoo da le lori.

Ẹni ti o fẹ ṣoniduro fun gbọdọ jẹ ẹni ti o mọ daadaa, dele dele, too mọ ọna rẹ. To da ọ loju pe yoo wa sile ẹjọ lọjọkọjọ ti ile ẹjọ ba sọ pe ko wa, ti ko ni salọ.

Ẹsun ti wọn ba si fi kan ẹni naa ni yoo sọ iru oniduro ti adajọ yoo sọ pe ko mu wa.

Owo ti ile ẹjọ ba sọ pe ki ẹ fi gba oniduro, kii se fun ile ẹjọ, o tumọ si pe iye owo ti o o san fun ile ẹjọ niyẹn ti ẹni to duro fun ba salọ.

Bakan naa ni dukia ti ile ẹjọ ba beere lọwọ rẹ, ile ẹjọ kọ lo ni i, ile ẹjọ yoo gba a ni ti ẹni naa ba sa lọ.

Awọn kan n fi ṣe oniduro gẹgẹ bi okoowo

Awọn kan ti wa to n fi jijẹ oniduro ṣe iṣẹ ṣe. Awọn gan an lo n ba ẹka ofin jẹ ni Naijiria. Awọn lo mn jẹ ki ẹni to n jẹjọ salọ. Wọn ko ni iṣẹ meji ti wọn n ṣe ju iyẹn lọ.

Ko si si bi adajọ ṣe fẹ ẹ mọ. Ti adajọ ko ba si ṣe iwadi daada ko n i mọ. Ti ẹni to n jẹjọ ba salọ, awọn naa yoo salọ.

Koda wọn maa n ṣe atọwọda iwe ilẹ, iwe ile, iwe ileesẹ ati bẹẹbẹ lọ lati fi tan ile ẹjọ.

Iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ sẹyin ni ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ nilu Abuja sọ pe ki awọn to ṣe oniduro fun olori ẹgbẹ́ to n polongo fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, Nnamdi Kanu, san ọgọrun un miliọnu ẹni kọọkan wọn sile ẹjọ.

Eyi ko ṣẹyin bi Kanu ti wọn duro fun ko ṣe yọju sile ẹjọ l'ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla ti igbẹjọ rẹ yẹ ko waye.

Awọn mẹtẹẹta, Sẹnetọ Enyinnaya Abaribe; alufa ijọ Juu kan, Immanuel Shalom, ati oluṣiro owo, Tochukwu Uchendu, ni onidajọ Binta Nyako paṣẹ fun lati san owo gọbọi naa si apo asunwọn ile ẹjọ.

Eyi lo mu BBC News Yoruba ba Amofin Sadiku Ibitayọ sọrọ lori awọn nkan to rọ mọ ṣiṣe oniduro fun ẹni to n j'ẹjọ.

Amofin ṣalaye pe oriṣi oniduro meji lo wa. Akọkọ ni eyi ti ileeṣẹ ọlọpa beere fun ati ti ile ẹjọ.

"Oniduro ti ileeṣẹ ọlọpa maa waye lasiko ti awọn ọlọpa ko ti i pari iwadi wọn lati mu ki ẹni naa duro fun afurasi ọdaran.

Wọn yoo kan sọ pe ki ẹni naa buwọlu iwe tabi fi iwe idanimọ rẹ silẹ. Awọn ọlọpa yoo pada ranṣẹ pe e ti o ba paa dandan."

Ni ti ile ẹjọ, awọn ti ẹsun ti wọn fi kan wọn ba fi aaye silẹ pe wọn le maa gba ile wọn wa jẹjọ ni adajọ maa n gba oniduro fun.