Shonekan -Mọ̀lẹ́bí Olórí Nàìjíríà nígbà kan rí ní kokoko lara rẹ̀ ẹ́ le

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

'Ìròyìn ẹlẹjẹ gba ni pe Aarẹ Naijiria nigba kan ri alagba Ernest Shonekan ti papoda.'

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile isẹ iroyin BBC, akowe ijọba ipinlẹ Ogun, Taiwo Adeoluwa so pe ''kokoko lara alagba Shonekan le.''

''Gomina Ibikunle Amosun ṣẹṣẹ ba olori Ìjọba fìdíhẹ́ lorileede Naijiria nigba kan ri sọrọ ni''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Bakanna ni awọn kan naa ti fi ikede soju opo Twitter pe ko si ootọ kankan ninu iroyin pe Shonekan wa ja

Iroyin iku rẹ yi tunbọ ṣe afihan aburu ti iroyin ẹlẹjẹ ma n ṣe lawujọ.

Ni kete ti ọrọ na lu si ayelujara ni awọn kan ti n kede iku rẹ lalai ṣe iwadi ẹkunrẹrẹ

Alagba Ṣhonekan to jẹ agbẹ́jọro ati oloseelu ti fi igba kan jẹ Aarẹ ijọba fidihẹ ri ni Naijiria lọjọ kerindinlọgbọn Oṣu kẹjọ ọdun 1993.

Oṣu mẹta pere lo lori aleefa ki ọgagun Sani Abacha to fipa gba ijọba lọwọ rẹ.