Ajimajasan; Àwọn ọmọ olóògbé gbóríyìn fún bàbá wọn
Awọn mọlẹbi ati ọmọ oloogbe Ọla Ọmọnitan ti gbogbo eeyan mọ si 'Ajimajasan' ba ikọ BBC Yoruba sọrọ lori igbe aye ati awọn ohun to ṣẹlẹ saaju ipapoda gbajugbaja adẹrinpoṣonu naa.
Bakan naa ni wọn mẹnuba lara awọn ohun ti wọn yoo ṣe afẹri ẹ nipa baba wọn.
Oloogbe Ọla Ọmọnitan jade laye l'ọjọbọ, ọjọ kejidunlogun, ọdun 2018 lẹni ọdun mejilelọgọrin lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.