Tọkọtaya méjì, ọmọ ìyá mẹ́rin bá ìjàmbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ l'Amerika

Èèyàn ogun ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ kan to waye nilu New York lorilẹede Amerika.

Ile isẹ ọlọpaa sọ pe ijamba naa sẹlẹ nigba ti ọkọ ayokẹlẹ to n gbe wọn lọ si ode ariya sadeede kọlu ọkọ miran ti o si ya lọ ba awọn eeyan ni iwaju ile itaja kan.

Gbogbo awọn eeyan mejidinlogun ati awọn eeyan meji kan to n lọ ti wọn jẹjẹ lẹgbẹ titi ba isẹlẹ naa lọ.

Ko ti si alaye nipa ohun ti o fa ijamba naa.

Bakanna ni wọn ko ti mọ awọn to farakasa ninu isẹlẹ ọhun sugbọn iwe iroyin New York Times sọ pe awọn ọmọ iya mẹrin kan wa lara awọn to ko ijamba yi ati awọn tokotaya meji kan naa.

Agbalagba ni gbogbo awọn to ku ninu ijamba ọkọ ohun.

Awako to wa ọkọ naa ba iselẹ ohun lọ.

Nigba ti o n ba awọn akoroyin sọrọ, alaga ajọ to n mojuto abo loju popo Robert Sumwalt ni ''iselẹ ọhun jẹ eyi to buru ju lọ nipa iye ẹmi to ku ati wi pe awọn ko ti ri iru ijamba ọkọ bee lati ọdun 2009.''