You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjàmbá Bàálù: Àjọ̀dún òmìnira ilẹ̀ wa ni wọn ń se lọ́wọ́, ni bàálù méjì já
Ileesẹ ologun ilẹ wa tun ti fi iroyin miran sita loju opo Twitter rẹ pe, tẹdun-tẹdun ọkan ni oun tun fi n kede iku ọkan lara awọn awakọ baalu kekere meji tileesẹ ọmọ ogun ofurufu ilẹ wa, to ja laarọ ọjọ Ẹti nilu Abuja.
Alukoro fun ileesẹ ologun ofurufu ilẹ wa, Ibikunle Daramọla, loju opo Twitter rẹ ni awakọ baalu naa, ti wọn ti saseyọri lati fa yọ ninu ọbaalu to ni ijamba naa, F-7Ni, lo papa jalaisi.
O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.
A ti kọkọ mu iroyin wa fun yin saaju pe, baalu kekere tileesẹ ọmọ ogun ofurufu ilẹ wa naa lo ja ni ilu Abuja, lasiko ti wọn n sàmì ayẹyẹ ominira ọdun kejidinlọgọta ti orilẹ-ede yii.
Akọroyin BBC to wa nibi isẹlẹ naa ni oke Katampe ni Abuja, ni isẹlẹ naa ti waye,
Ni kete ti baalu kekere naa si ja, lo gba ina, lasiko isẹlẹ naa to waye ni deede aago mọkanla aarọ ọjọ Ẹti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọkọ ofurufu kekere naa, to n fo pẹlu awọn mẹta miran lo sadede ja lulẹ.
Iroyin naa ni ọkan ninu awọn ologun ọhun, ẹni to lo ohun idaabo loju ofurufu tawọn oloyinbo n pe ni Parachute, lo papa jẹ Ọlọrun nipe.
Awọn ọkọ ofurufu bii mẹta miran la gbọ pe wọn n ra baba loju ọrun nibi ti isẹlẹ naa ti waye.
Alukoro fun ileesẹ ologun ilẹ wa, Ibikunle Daramọla, to fi idi isẹlẹ naa mulẹ ni, ọkọ ofurufu meji lo ba ijamba naa rin.
Daramọla, ẹni to fidi isẹlẹ naa mulẹ loju opo Twitter ileesẹ ologun ofurufu ilẹ wa ni.
Bẹẹ ba si gbagbe, ileesẹ ologun ofurufu Naijiria lo ti kede saaju pe oun yoo se idanrawo loju ofurufu gẹgẹ bii ara eto to n sami ayẹyẹ ọdun kejidinlọgọta tilẹ wa gba ominira.