You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìyá Darasimi: Ọlọ́run fi ìbejì rẹ̀ mí lẹ́kún, lẹ́yìn ikú Darasimi tó mu sódà
Èyí ni itan bi Darasimi Ogunwunmi, to jẹ ọmọ ọdun mẹta se mu omi soda ti olukọ rẹ gbe silẹ nile ẹkọ, nigba ti oungbẹ n gbẹ.
Darasimi lo bu omi soda naa mu, nigba ti olukọ rẹ ko tete da lohun lati fun ni omi mu.
Lẹyin isẹ abẹ mẹta ọtọọtọ, Darasimi ko lee jẹun mọ, nkan olomi lo n mu, titi to fi jade laye.
Ọlọrun wa rẹ awọn obi rẹ lẹkun lẹyin osu mẹsan ti Darasimi ku, pẹlu ibeji ọkunrin lanti-lanti.