You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Banky W: ojoojúmọ́ ayé mi ni mo ti fi lá àlá kó lè wá sí ìmúṣẹ
Olorin Takasufe Bankọle Wellington ti kéde loju opo twitter rẹ pe òun ti fẹ mu ìran oṣelu ṣẹ laye oun ni 2019.
O ni oun mọ pe oun kò ni baba isalẹ ti ọpọ gbà pé o ṣe pataki sí oṣelu Naijiria ṣugbọn oun gbagbọ ninu Ọlọrun.
O sọrọ nipa àwọn nkan bii ọgbọn inú ati ootọ inu ti oun fẹ lo fi dupo aṣojuṣofin fun àwọn eniyan Eti Ọsa nilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.
Banky W. ṣalaye pé oun nigbagbọ ninu agbara oludibo ati ireti awọn eniyan Naijiria lati ni ọjọ iwaju rere ti ko ṣẹyin awọn adari to bẹru Ọlọrun.
O ni o tẹ́ oun lọrun lati gbiyanju wo boya oun a wọle tabi bẹẹ kọ ju ki oun kan fọwọ lẹran lasan lọ lasiko yii.
Banky W. ni Modern Democratic Party ni ẹgbẹ oṣelu to fẹ dije ninu rẹ, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ẹgbẹ oṣelu ti pari idibo abẹle wọn lati yan oludije ninu idibo 2019 ṣugbọn ajọ eleto idibo INEC ti kede pe aaye ṣi wà fáwọn ẹgbẹ oṣelu lati paarọ àwọn oludije wọn.
Banky W padanu ọmọ
Ìkíni ibanikẹdun ko dúró lórí ikú ọmọ Dbanj
Ìròyìn ikú ọmọ Dbanj jẹ́ nnkan tí o kò òpó ọmọ orílèèdè Nàìjíríà nínú.
Ikú, bo je t'ọmọdé tàbí àgbà jẹ nnkan tí ó máa ń ba ni nínú jẹ.
Kété ti ìròyìn jáde ní àwọn èèyàn tí n ki Oladapo Daniel Oyebanjo ku ara feraku ọmọ rẹ.
Ruggedy Baba to je ilumoka olorin takasufe wa lara awọn to fi ikini ransẹ.
Banky W naa sọ pe iroyin ọ̀hún fọwọ ba oun lẹmi tohun ti iroyin isẹlẹ ipaniyan to waye ni ipinlẹ Plateau
Olamide ati Davido ko gbẹyin