Ẹgbẹ APC ti kéde ọjọ́ tuntun fún ìdìbò abẹ́nú ní Ekiti

Oríṣun àwòrán, APC NIGERIA
Ẹgbẹ òṣèlú APC ti kéde ọjọ fún ìdìbò abẹ́nú láti yan eni ti yóò gbé àsìá gẹgẹ bí oludije ipò Gómìnà nipinle Èkìtì.
Ọgbẹni Bolaji Abdullahi, akòwé ìpolongo ẹgbẹ, ló lédè ọrọ náà fún àwọn akoroyin nílu Abuja.
Ìgbìmò eleto ìdìbò ẹgbẹ náà ti sáájú fí èsì ìwádìí lórí òun tó fà ikọlu nibi ìdìbò abẹnu nipinle naa ṣòwò si alága ẹgbẹ lójó ìṣẹgun.
Ẹgbẹ pinnu láti ṣe ìwádìí ìṣẹlẹ náà.
Olùdíje mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ni o n kópa nínú ìdìbò náà ti a ti ri Gómìnà nígbà kàn ri méjì àti Senato nígbà kan rí mẹta nínú wọn.








