Wọ́n so ìdìbò APC rọ̀ l'Ekiti nitori rògbòdìyàn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iroyin to kan wa lọwọ sọ pe wọn ti so idibo abẹle ti ẹgbẹ oṣelu APC ti o waye l'oni ni Ado Ekiti, Ipinlẹ Ekiti rọ latari wahala ti o ṣẹlẹ nibi idibo naa. A pe alukoro ẹgbẹ naa kan ṣugbọn kò jẹ́ ipe wa lati sọ bi o ṣe jẹ́.

Ipinlẹ Nasarawa ti gomina wọn Tanko Al-Makura n ṣe akoso ibo naa sọ lori Twitter pe ni tootọ ni wahala ṣelẹ ṣugbọn pe gomina naa ti pe awọn oludije si ipade lati dẹkun ọrọ naa.

Ọkan lara awọn oludije nibi idibo naa Femi Bamiṣilẹ ti o ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade naa ni, ẹgbẹ APC yoo jiórò lori ọrọ naa ki wọn to mọ oun ti wọn maa ṣe.

A gbọ pe wahala bẹ silẹ nibi idibo abẹle APC ni Ado Ekiti, ti awọn agbofinro si yinbọn soke lati dọwọ iṣele naa.

Ni ori Twitter, awọn tí o wa nibẹ sọ wipé awọn kan tilẹ̀ ti ji apoti ibo gbe, ti awọn olukopa kan si fọ awọn apoti.