You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Nàìjíríà kìlọ̀ ìṣọ́ra ní ìlú London
Ijọba orilẹede Naijiria ti kilọ fun awọn ọmọ ilẹ naa to wa ni ilu London lati ma a sọ ara se nitori iṣekupani to n waye lagbeegbe naa.
Oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ ilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa ni oun ibanujẹ lo jẹ fun oun bi awọn alawọdudu, paapaa awọn ọmọ Naijiria se n padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ni ilẹ Geesi kọ oun lominu.
Ile isẹ arabinrin naa ni wipe lati ibẹrẹ Osu kini, Ọdun yii, ọdọ to jẹ alawọdudu aadota, 50 ni wọn ti gun lobe tabi ti won yin ibon pa ni ilu london.
O fi kun wipe mẹsan ninu awọn ti wọn sekupa naa jẹ ọmọ Naijiria to wa ni ilu London ati awọn agbeegbe miran ni ilu Geesi
Arabinrin Dabiri-Erewa naa fikun wipe oun ti kọ lẹta ifẹhọnu han si asoju ilẹ Geesi ni Naijiria, ti oun si bẹrẹ fun iwadii ati idajo otito lori isẹlẹ naa.