You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjà jàǹdùkú ní'jẹ̀bú: Ọ̀gá ọlọ́pàá, aráàlú mẹ́rin ku
Kò dín ní ẹ̀mí márùń, nínú èyí tí a ti rí aráàlú mẹ́rin àti Ìsìpẹ́kítọ̀ ọlọ́pàá kan, tó ku nínú ìpórógan tó wáyé láàrin ẹgbẹ́ kan tí àwọn èèyàn funra sí pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ àwọn jàǹdùkú kan láti ẹgbẹ́ OPC àti ẹgbẹ́ òkùnkùn kan ní ìlú Ìjẹ̀bú Igbó lọ.
A gbọ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé òṣèlú kan tó wáyé láàárín igun óṣèlú méjì kan lágbègbè náà.
Aago márùń ààbọ̀ ìrọ̀lẹ́ lọ́jọ́ àìkú ni ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní agbègbè Òkè-Sopen, tó sì sún wọ ìdàjí ọjọ́ ajé, èyí tó tún tàn wọ àwọn àdúgbò míì bíi Òkè Àgbò àti Ojowo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Àwọn èèyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sojú wọn ní ààrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC kan àti ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiyé ni rògbòdìyàn náà ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, kí àwọn ọlọ́pàá tó dá síi, tí ẹ̀mí ọmọ ẹgbẹ OPC kan sì bọ́.
Àlàáfíà ti ń padà jọba lágbègbè náà
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni awọn ti ko ikọ Olopaa kogberegbe lọ si agbegbe naa lati lọ wawọ́ ọ rogbodiyan naa bọlẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ni gbogbo awọn ti aje rogbodiyan naa ba ṣi mọ lori ni yoo fi oju wina ofin.
Wàyí ò, iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn ti ń ri dájú pé àlàáfíà ti ń padà jọba lágbègbè náà.