Ikọlu Yobe: Ijọba apapọ taari ọga ọlọpa si Dapchi

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Minisita fun ọrọ abẹle lorilẹede Naijiria, Ajagunfẹyinti Abdulrahaman Dambazau ti paṣẹ fun ọga-agba ọlọpaa ati akẹgbẹ fun ileeṣẹ aabo-ara-ẹni-laabo-ilu, (Civil Defence) lati tẹ ọkọ leti gba ẹkun ila oorun ariwa orilẹede yii lọ.
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria n fẹ ki aabo wa fawọn akẹkọ lẹkun ila oorun ariwa orilẹede yi.
Eyi ko ṣẹyin wahala to n bẹ silẹ lẹkun ọhun.
Aṣẹ naa tun fi kun un wipe ki awọn ọga agba ileeṣẹ mejeeji yii o lọ forikori pẹlu olori ikọ ọmọogun 'Lafiya Dole' to n k'oju awọn agbesunmọmi nibẹ.
O ni wọn yoo jiroro lori lọna ati lee jumọ ṣiṣẹ pọ ki alaafia lee pada si agbegbe naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Minisita fun ọrọ abẹle lorilẹede Naijiria tun paṣẹ pe ki awọn mejeeji o joko pọ ṣe'pade pẹlu awọn gomina ipinlẹ Yobe, Borno ati Adamawa.
O ni ipade naa gbọdọ da lori ati lee ṣeto bi awọn oṣiṣẹ ọlọpa ati ileeṣẹ abo-ara-ẹni-laabo-ilu, (Civil Defence) yoo ṣe maa pese aabo l'awọn ileewe gbogbo to wa lẹkun naa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajagunfẹyinti Dambazau ni aṣẹ yii di ọranyan lati lee dẹkun akọtun ikọlu sawọn ileewe ati akẹk, irufẹ eyi tawọn ikọ agbebọn Boko Haram ṣe nilu Chibok ati ni kopẹkopẹ yii nilu Dapchi nipinlẹ Yobe.












