Ọdọ kan sọrọ lori ipalara aibuwọlu abadofin Peace corps

Pẹlu bi aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti se da abadofin idasilẹ ajọ Peace Corps silẹ nu bayii, oniruuru iroyin to n jade bayii ni ti awọn ọdọ to wa ni ajọ naa ti wọn ti n mi imi ẹdun bayii lori igbesẹ naa ti wọn ni o jasi wi pe owo awọn wọgbo.

Ohun ti BBC Yoruba gbọ ni wi pe awọn ọdọ to wa lajọ yii ni wọn san owo fun ati wọle si bẹ.

BBC Yoruba ba ọkan ninu awọn ọdọ yii sọrọ sugbọn a fi orukọ boo laṣiri.

Ninu ifọrọwerọ ni o ba BBC Yoruba ni o ni ijakulẹ ireti patapata ni isẹlẹ naa jẹ nitori awọn alasẹ ajọ naa ti fi wọn lọkan balẹ wi pe isẹ yoo bọ sii fun wọn nipasẹ ajọ naa.

"Ọpọlọpọ eeyan lo ti kọwe fi isẹ wọn silẹ ni ireti wi pe ọrọ peace corps yii yoo tete jasi nitori ohun ti wọn sọ fun wa ni wi pe wọn ko ni pẹ buwọluu sugbọn ọdun meji lawa yii ti wọn ko tii buwọlu ki aarẹ tilẹ to wa sọ wipe ọrọ o lee ri bẹẹ mọ bayii."

Ohun ti ọdọ kọọkan la kọja ki o to wọ ajọ Peace Corps

"Nigba ti awa naa dẹ wo eyi gẹgẹbi ọna kan ati ri isẹ a gba fọọmu ẹgbẹrun kan abọ naira ni ileesẹ wọn. Igbati a gba fọọmu tan, wọn ni a maa san ẹgbẹrun lọna ogoji naira fun owo ẹkọsẹ.

"Pe owo yii ni yoo jẹ owo asọ isẹ, awọn ohun elo isẹ gbogbo. Awọn eeyan miran gan san ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

"Fun awọn eeyan to san ẹgbẹrun lọna aadọta naira bata tapa sẹgun ti wọn fi n sisẹ wa nibẹ sugbọ fun awọn to san ẹgbẹrun lọna ogoji, ko si bata yii nibẹ.

"Ẹgbẹrun lọna ogoji lemi san nitori mo sọ fun wọn pe mi o fẹ bata tapa sẹgun yii.

"Ọọfiisi wọn lemi ti se ẹkọsẹ ni temi fun ọsẹ meji.

"Lẹyin ẹkọsẹ yii wọn tun ni ki a san awọn owo pẹpẹpẹ bẹrẹ lati igba naira si ẹgbẹrun meji naira. A san owo fun kaadi idanimọ ati lẹta atẹransẹ SMS pẹlu.

"Laipẹ yii a tun san owo ayipada kaadi idanimọ kan to jẹ ẹgbẹrun mẹwa naira.

"Pupọ owo yii ni kii se ileefowopamọsi lo gbaa sugbọn ọfiisi wọn ni a san an si.

"Ohun ti wọn si sọ fun wa ni wipe lati oke ni asẹ owo yii ti n wa. Lọpọlọpọ igba gan an ni wọn maa tun n halẹ mọ wa wipe ti a ko ba san owo yii, orukọ wa o ni jade. Ibẹru yii lo maa n jẹ ki pupọ ninu wa o san owo yii.

"A ti gba fun Ọlọrun. A ti gba kamu nitori kan si nkan ti a lee se.

"Ti aaye rẹ ba yọ funmi maa beere owo mi pada nitori ko rọrun lati ri owo yii.

"Arọwa temi ni wipe ki ijọba tun fi oju miran wo ọrọ yii".

N jẹ lootọ ni ajọ Peace Corps gba owo ki awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ to darapọ?

Alukoro ajọ naa, arabinrin Millicent Umoru to fi idi rẹ mu lẹ wi pe lootọ ni wọn gba owo to to ẹgbẹrun lọna ogoji naira lọwọ awọn ọdọ naa sugbọn kii se owo afi ipa gba.

"Alukoro ajọ Peace Corps ni owo asọ isẹ ati ẹkọsẹ ni owo ti wọn gba.

"Ki o to lee darapọ mọ ajọ yii, eniyan bẹẹ yoo ti wo fọọmu igbaniwọle ninu eyi ti a ti ṣe alaye ohun ti owo ti wọn san wa fun.

"A ko fi ipa mu awọn eeyan wọnyii lati san ẹgbẹrun lọna ogoji naira yii. Ohun to wu olukuluku ni lati san an"

Kini yoo sẹlẹ si owo ti wọn san bayii?

Ajọ naa ṣalaye siwaju sii wipe ko si idi ati da owo pada fun ẹnikẹni nitori owo naa ni wọn fi se eto ẹkọsẹ wọn ati asọ isẹ wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: