Timothy Adegoke: Nígbà tí máa fi kúrò níbi iṣẹ́, ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV ṣì ń ṣiṣẹ́- Adedeji Adesola

Bí ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke ṣe ń tẹ̀síwájú nílé ẹjọ́ lónìí Adesola Adedeji tí takò ọ̀rọ̀ Adeniyi Aderogba, O ni ẹrọ ayaworan CCTV n ṣiṣẹ́ ni ojo Karùn-ún oṣù konkanla ọdún 2021

Oṣisẹ ile ìtura Hilton Hotel Honour ati ọkan lara awon afurasi to n jẹjọ lori iku Timothy Adegoke akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, Adedeji Adesola ni pe ẹrọ ayaworan CCTV n ṣiṣẹ́ nígbà tí òun fi maa kuro nibi isẹ ni ojo karun-un oṣù kọkanla ọdun 2021.

Adesola ni oun iyalẹnu ni ò jẹ fun oun nigba ti oun padà sí ẹnu iṣẹ ni ojo kesan oṣu kokanla ọdun 2021 tí òun sì rí ẹrọ ayaworan CCTV tí o ti dẹnu kọlẹ.

"Ẹrọ ayaworan CCTV ń ṣiṣẹ́ nigba ti maa fi kuro nibi isẹ ojo Karun-un oṣu kokanla ọdun 2021.

"Oun iyalẹnu ni o jẹ fun mi nigba ti mo rí ẹrọ tẹlifiṣan plasma to máa n wa nibi tí àwa "receptionist" máa ń duro si ti ko ṣíṣe mọ."

Ti ẹ o ba gbagbe, ọkan lara awon afurasi naa Adeniyi Aderogba sọ fun Ile ẹjọ́ giga ìpínlẹ̀ Osun labẹ akoso Adájọ́ Adepele Ojo pe ẹrọ ayaworan CCTV tí bajẹ láti igba ti wọn ti ṣe atunse si ile ìtura naa.

Aderogba sọ fún ilé ejò pe ki iṣẹlẹ iku Timothy Adegoke akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo to waye ni ẹrọ ayaworan CCTV tí bajẹ.

Eyi ni olujẹri keje to n jẹri nipa ohun to mọ nipa iku oloogbe Timothy Adegoke nile ẹjọ giga ilu Osogbo.

Ninu fidio ti BBC Yoruba ṣe ni ibẹrẹ igbẹjọ naa lowurọ ọjọ Aje la ti rii ti awọn afurasi to n jẹjọ lori ẹsun naa n wọ inu ile ẹjọ lọ lati lọ wi tẹnu wọn.

Awọn to n jẹri ti n sọ bi wọn ṣe gbe oku arakunrin naa lati inu ile itura ọhun lọ si ọna Ede.

Bakan lara awọn Dokita to ṣe ayẹwo oku toun naa wa ni ile ẹjọ sọ ọrọ kan to jọ mọ pe o ṣeeṣe ki iku Timothy ma ni ọwọ eeyan ninu.

Timothy Adegoke jẹ akẹkọ imọ ẹkọ onipele Masters ni Fasiti Obafemi Awolowo to si lọ fun idanwo rẹ ni Ile- Ife lo ṣe gba yara si ile itura Hilton Hotel.

Awọn mta kan jẹwọ pe awọn lawọn gbe oku rẹ kuro nile itura naa ti wọn si lọ ju oku rẹ si ọna Ede ti wọn si tun ni Raheem ọmọ Ramon lo ni ki awọn ṣe bẹẹ.

Wọn ti fi ẹsun kan Oloye Ramon Adedoyin ati ọmọ rẹ Raheem Adedoyin pe wọn lọwọ ninu iku oloogbe naa to ku si ile itura to jẹ tiwọn.

Bakan naa, awọn olujẹri oniruuru lo ti n wi tẹnu wọn lori ẹsun yii paapaa awọn to jẹ oṣiṣẹ ile itura Hilton.

Awọn Agbẹjọro to n duro fun ẹbi Timothy Adegoke ni:

Femi Falana

M.O Omashun

A.A Adegoke

Fatima Adeshina

Femi Akinyemi

Bakan naa, awọn agbẹjọro to n duro fun olujẹjọ, iyẹn idile Adedoyin ni:

K.K Eleja

Williams Ajayi

Adewole ọláire

Ibrahim Alabidun

A.O Olajide