You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sylvester Oromoni: Mọ̀lẹ́bí Buruji Kashamu sọ̀rs sókè lórí ẹ̀sùn pé ọmọ rẹ̀ wà lára àwọn tó fìyà jẹ olóògbé
Idile Oloogbe Sẹnetọ Buruji Kashamu, ti ko ẹsun pe Adewale Kashamu ọmọ ologbe naa ni ọwọ ninu iku Sylvester Oromoni Jnr danu.
Oromoni, ẹni ọdun mejila akẹkọọ Dowen to ku ni ọjọ melo kan sẹyin lẹyin ti wọn ni awọn asiwaju rẹ nile ẹkọ to n lọ lo luu nitori pe o kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Wọn sọ pe ọmọ to ku naa mẹnuba ọmọ aṣofin to ti di ologbe pẹlu awọn ọmọ ile-iwe mẹrin miiran ṣaaju ki o to ku.
- Àwọn mọ̀lẹ́bí Sylvester Oromoni bẹ Femi Falana lọ́wẹ̀ láti pe Dowen College lẹ́jọ́
- A ṣetán láti bá Sanwo-Olu rìnrìn àlàáfíà, ẹ̀yin krìstẹ́nì, ẹ darapọ̀ mọ wa- MURIC
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
- Àbùkù ńlá ni ikú Sylvester Oromoni jẹ́ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó- ìyàwó Gómìnà Sanwo-Olu
- Fásitì fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún olùkọ́ tó nawọ́ eré ìfẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́
Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti Mutairu Kashamu fowo sì, l'orukọ idile Adewale lọ ti sọ pe oun ko lu Oromoni tabi tabuku rẹ gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan.
Gẹgẹ bi atẹjade tí ẹbi fọwọsi ṣe sọ, Adewale mọ Oromoni ni igba akọkọ rẹ ni kọlẹji, eyiti o ṣi ṣe bi baba ile-iwe rẹ gẹgẹ bi ẹgbọn obinrin oloogbe ti béèrè fun, tí oun naa jẹ ọmọ ile-iwe yẹn lasiko naa.
Ẹbi naa sọ pe ibaraẹnisepo Adewale pẹlu Oromoni dinku ni asiko ikẹkọ 2021 lẹyin ti wọn gbe lọ si ile ti o yatọ sibi ti awọn akẹkọọ naa n gbe.
Atejade ọhun sọ pe Adewale ko mọ nipa lilu ti wọn lu ọmọ naa ti o si wa pada gba ẹmi ọmọ rẹ.
Idile naa ṣafikun pe ọmọ awọn ti kọkọ ri Oromoni ni Oṣu kọkanla ti o n tiro ati pe o farapa lakoko ti o n gba bọọlu, ó si gba ni imọran lati ṣabẹwo si ile-iwosan ti ile-iwe naa.
O tun sọ pe awọn ọmọ ile-iwe miiran ti o mọ nipa ipalara ẹsẹ Oromoni jẹri pe o farapa lakoko to n gba bọọlu pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni.
Ebi naa sọ pe awọn o kọkọ sọrọ lori iṣẹlẹ naa, lati jẹ ki wọn ṣe iwadii to yẹ kí awọn to fesi si awọn "abuku" ti awọn eniyan n sọ lati igba ti iroyin iku Oromoni ti jade.
"Lati igba ti iroyin iṣẹlẹ aburu ti iṣẹlẹ a ti tẹ ọmọ wa ninu ti a si ti ṣe awọn ibeere ikọkọ tiwa lọwọ ọmọ wa ni pẹkipẹki lati mọ bi ọrọ ṣe kan."
"Nitori idi eyi ni a ko fi yara jade lati dahun si igbe to n lọ lori ayelujara, pipe orúkọ ẹbi wa ni ilodi ati awọn isọkusọ odi ti o ti gba lori oju opo ikansiraẹni gbogbo nipa ilọwọsi ọmọ wa pe o ni ọwọ ninu iṣẹlẹ ibanujẹ yii.
"Ẹbi naa rọ awọn araalu lati duro de abajade iwadii ijọba ipinlẹ Eko ati ọlọpaa lori ohun to fa iku Oromoni.
"A ni imọlara a si mọ awọn irora ti idile Oromoni ati gbogbo awọn ti o ni ifẹ si nitootọ nipa iṣẹlẹ yìí n laa kọja "o fikun.
"Idi niyi ti a fi n setan lati fọwọsowọpọ pẹlu, awọn obi oloogbe naa, awọn ọlọpaa , Ijọba ipinle Eko àtàwọn ti ọrọ kan lati wa isu de isalẹ koko lori ọrọ yii ki idajọ ododo ba le han gbangba lori gbogbo awọn to lọwọ nibẹ."
- Ní kíákíá ẹ yí ìpinnu yín padà sí Nàìjíríà lórí ẹda ààrùn COVID-19 Omicron-Lai Mohammed
- Adama Barrow wọlé sáà kejì sí ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Gambia
- Ẹ̀ wo bàbá àgbàlagbà tó lo ayédèrú apá nitorí kò fẹ́ gba abẹrẹ́ àjẹsára Covid-19
- Àwọn akọrin ìjọ tó fẹ́ lọ ṣe ìgbéyàwó kàgbákò òjò àrọ̀rọ̀dá, ẹ̀mí 23 sọnù...
- BBC kéde àwọn tó pegedé láti gba àmì ẹ̀yẹ èrè ìdárayá ọdún 2021
- Báwo ni àwọn ọmọ méje ṣe di òkú sínú ọ̀kọ̀ àyọkẹ́lẹ̀ kan ní Badagry
"Sibẹsibẹ, o jẹ nnkan to bani lọkan jẹ pe ninu awọn orukọ marun ti wọn mẹnuba pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, orukọ Kashamu nikan ni o dabi pe o dùn bí agogo leti gbogbo eniyan Nitori bẹẹ, idile Kashamu ti ń kojú ọrọ abuku nigba ti awọn alaye kikun ko ti jẹyọ lori isẹlẹ naa.
Ko si bojuboju nibẹ pe Adewale Michael Kashamu je ọkàn lara àwọn ọmọ Oloogbe Alagba Buruji Kashamu, ṣugbọn, ko si idile tabi obi ti yoo fi ọmọ ranṣẹ si ile-iwe lati lọ kopa ninu eyikeyi iru iwa yii tabi lati lọ huwa ọ̀daràn, gẹ́gẹ́ bí inú òbí náà ko se ni dùn láti sọ pé ọmọ tí ó rán lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ni awọ́n akẹkọọ mìíran tàbí olukọ ń ṣe basubasu nitori idi yoo wu ko jẹ.
Ẹbi kashamu pari atẹjade na pe "Nitori idi eyi a fẹ lati bẹbẹ fun ikoraẹni ni ijanu ni gbogbo ọna. Pípa ẹbí wa laya lori ayelujara kii yoo ṣe iranlọwọ kánkán lati yanju ipanilaya laarin awọn akẹkọọ nile ẹ̀kọ́ ni awujọ nitori ó t wa tipẹ.
"Ní ìhà tiwa a ti ń bá ọmọ wa, Adewale Michael Kashamu sọrọ, ó sì ń sọ fun wá pe oun ko mọ ọwọ mọ ẹsẹ ninu ọrọ náà."