Women marry trees: Àwọn obìnrin ń ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú igi láti ṣàfihàn ètò idagbásókè tuntun ní Bristol

O kéré tan àwọn obìnrin tó le ni aadọ́rin lo ti ṣe ìgbáyàwó pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye igi níbi ayẹyẹ ti wọn fi ń ṣàfihàn bí àwọn ilé tuntun yóò ti ṣàkóba fún àwọn igi nítorí wọ́n yóò wú wọn kúrò.

Àwọn alagbátẹ́ru sọ pe ó n kọ awọn lóminu nípa ìnira ti ilé tó lé ọgọ́run-ùn àti mẹ́rìndínláàdọ́rin n da silẹ lori ilẹ Bristol.

Olùṣagbátẹ́rù ètò náà Siobhan Kierans sọ pé ìrétì oun ni pé ayẹyẹ yii ṣàfihàn pé awọn ìgi jẹ́ alábàrìn wa titi láì.

Ìjọba ibilẹ Bristol sọ pé nítorí awọn ìpinu awọn ètò to wà nílẹ̀ oun ko ni le fèsì lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó tó ṣe ayẹyẹ lọ́jọ́ náà láti oríṣiríṣi aṣa àti iṣe ti wọn si ṣàfihan pe awọn ń ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú igi mẹ́rinléláàdọ́rin fún awọn tó n ṣe ayẹyẹ.

Olupolongo tó tún wà lára ìyàwó Suzan Hackett láti Bristol: "Lati ṣe ìyàwó pẹ̀lú igi jẹ àǹfàní gidi kìí ṣe ọ̀rọ̀ ojú, sùgbọ́n nǹkan to se gbòógì ni.

Igi jẹ àpẹrẹ ifẹ́ aláìlẹ́tàn, ti a le fi ṣe apejuwe nnkan ti igbeyhawo tunmọ si, Títí ayeraye ni eto igbeyawo, ti ẹ o jọ maa mi titi lai.

"Bristol nilo awọn Igi ti o ti tojuubọ jhú kikọ ile igbalode sibẹ lọ

Eto ikọle ti wọn fẹ se lati Goram Homes ati Developers Hilla, ti ijọba ko tii buwọlu wa fun ile igbe to le ni ọgọrun to fi mọ awọn ile alabọde bi mẹ́rindinlaadọrin miiran.

Ẹni to ni Baltic Wharf Caravan ti igi mẹrinlelaadọrin wa ni ijọba ibilẹ ti kọwe ikilọ si pe ki o kuro nibẹ.

Iwe ti wọn kọ ransẹ naa ni pe awọn yoo nilo lati wu gbogbo igi to wà nibẹ, sugbọn ẹgbẹ Save Baltic Wharf Trees ati ti Bristol Tree Forum ti bẹnu atẹ lu nnkan ti wọn pe ni iwa ai lootọ nipa iye igi ti wọn fẹ́ wo ni agbegbe naa ati igba ti wọn fẹ woo.

Ọjọgbọn John Tarlton, to n jẹ onimọ nipa eto isegun ni Bristol Vetinary to kọ awọn igi bura to si tun peju gẹgẹ bi ọrẹ ọkọ nibi ayẹyẹ naa sọ pe, niwọn igba ti wọn ti buwọlu iwe pe ki iṣẹ bẹrẹ nibẹ, asọ o bọmọyẹ mọ.

"Ko ṣeeṣe kia padanu igi mẹrinlelaadọrin. O ti pọ ju fun awọn igi to ti gbọnju ati pe ni iha Bristol ti o ti wan ti nilo rẹ julọ lo ti n waye."