Nigeria Army and ISWAP: 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'

Ileesẹ ologun Naijiria sọ pe ikọ ọmọ ogun Operation Hadin Kai pẹlu ajọsepọ àwọn ọmọ ogun oju ofurufu pa aadọta lara awọn ọmọ agbesunmọmi Islamic State West Africa Province (ISWAP).

Ọjọru ni ileesẹ ologun sọ pe iṣẹlẹ naa waye, nibi ti awọn ọmọ ogun tun ti ba awọn ọkọ ijagun agbelẹrọ to jẹ ti ẹgbẹ ISWAP.

Eyi di mimọ ninu atẹjade ti Oludari ẹka ibaraalu sọrọ nileesẹ ologun, Mohammed Yerima, fi sita.

Oleeṣẹ ologun ni "igbiyanju ẹgbẹ ISWAP lati kọlu ijọba ibilẹ Damboa, nipinlẹ Borno ja si òfo, nitori bi awọn ọmọ ogun Naijiria ṣe kapa wọn."

O ni orisirisi àwọn nkan ijagun, ati ado abugbamu ni awọn eeyan naa ko dani, pẹlu ọkọ ijagun ati ọkada.

Ileṣẹ ologun ni: "Àmọ́ bi agbara àwọn ọmọ ogun Naijiria ṣe ká wọn, mu ki aadọta lara wọn ṣubú, ti awọn to ku si salọ.

"Ọga Agba ileesẹ ologun, Major General Faruk Yahaya si ti ki awọn ọmọ ologun ku oriire, fun àṣeyọrí nla naa.

Bakan naa lo sọ pe afojusun ileesẹ ologun, labẹ ìṣàkóso oun ni lati fi opin si igbesunmọmi ati awọn iwa ipanle mii to n waye ni Ila Oorun Ariwa Naijiria.