You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lagos -Ogun Tanker Explosion: Ọkọ̀ agbépo kan tí gbiná lórí afárá Magboro
Ijamba ina tun ti waye nipinlẹ Ogun lẹyin ti ọkọ agbepo gbina ni opopona Magboro, ọna lati wọ ipinlẹ Eko.
Awọn ẹṣọ oju popo ati awọn panapana ti wa nibẹ lati doola ẹmi awọn eniyan gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Idaji ni iṣẹlẹ naa waye, ti ko si tii si ẹni to mọ ohun to fa iṣẹlẹ naa.
Ẹṣọ oju popo ti gba awọn eniyan nimọran lati gba ọna miran yatọ si opopona Ibadan si Eko.
Eyi n waye lai tii pe oṣu kan ti iru iṣẹlẹ naa waye, ti o si mu ẹmi eniyan mẹta lọ.