Taribo West: Agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà wọ gàu lọ́wọ́ ọmọ Náìjíríà lórí àsọtẹ́lẹ̀ pé Trump yóò wọlé ìbò ààrẹ Amerika

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Taribo West wọ gàu lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà lẹ́yìn tó sọtẹ́lẹ̀ pé Trump yóò wọlé ìbò ààrẹ Amerika.

Ọrọ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Taribo West lọpọ n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara lẹyin to sọ asọtẹlẹ pe Aarẹ Donald Trump ni yoo wọle ibo aarẹ orilẹ-ede Amẹrika.

Ọpọ lo bẹrẹ si ni fi West to jẹ adilemu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ṣe lẹyin ti oludije ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden wọle ibo ọhun tan.

Fidio asọtẹlẹ naa ti wa lori ayelujara ṣaaju ibo aarẹ Amẹrika, amọ awọn eeyan bẹrẹ si ni sọ nipa rẹ lẹyin ti Trump fidi rẹmi tan.

West to jẹ pasitọ sọ ninu fidio naa pe oun sọtẹlẹlẹ ṣaaju pe Godwin Obaseki ni yóò wọlẹ ibo gomina ipinlẹ Edo.

O tun sọ ninu fọ́nrán naa pe asọtẹlẹ jade lẹnu oun pe Rotimi Akeredolu ni yoo wọle ibo gomina Ondo, ṣugbọn ko si ẹni to sọ nipa awọn asọtẹlẹ yii lori ayelujara.

O rọ eeyan lati pin fidio naa nitori pe o da oun loju pe ibo diẹ ni Trump yoo fi la Biden mọlẹ ninu ibo aarẹ Amẹrika.

Amọ, awọn kan sọ pe asọtẹlẹ Ọgbẹni West si le wa si imuṣẹ nitori Trump ti gbọrọ idibo naa lọ si ileẹjọ.