Afam Power Plant: Àwọn ọmọ Nàíjíríà fèsì sí ìjọba àpapọ̀ tó ta Afam Power Plant

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti ṣe ayẹyẹ ibuwọlu tita ileeṣẹ amunawa, Afam Power Plant ati Afam Three Fast fun ileeṣẹ aladani.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo ati Alaga Ajọ to n risi ọrọ ileeṣẹ aladani(NCP) lo wa ni ibi ayẹyẹ naa ni Abuja.

Ileeṣẹ to n moju to ina ọba ni Naijiria naa ni naa ni ipinlẹ Rivers, lorilẹede Naijiria.

Loju opo Twitter, Tony Elumelu fi lede wi pe inu ohun dun lati buwọlu iwe adehun to fun awọn ni ipese ina ọba to to 1000MW.

O fikun wi pe awọn ra a ni marunlelọgọrun biliọnu naira ni ọwọ ijọba apapọ Naijiria, ati wi pe awọn yoo ri daju wi pe ipese ina mọnamọna gooro si lorilẹede Naijiria.

Amọ igbesẹ ijọba yii ko dun mọ awọn eniyan ninu nitori naa ni wọn ṣe n fi aidunu wọn han lori ayelujara.

Ẹlọmiran ni ijọba kọ lati sọ fun wọn idi ti awọn fi ta ileeṣẹ mọnamọna naa.

Amọ, awọn kan gboriyin fun ijọba lori igbeṣẹ naa, ti wọn si lero wi pe eyi yoo mu ilọsiwaju ba ina ọba lorilẹede Naijiria.