You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Slave Trade Descendant: Wo àwọn ìran ẹrú tí kìí lọ́kọ tàbí aya ní Nàìjíríà
Owo ẹru ni Naijiria waye nigba ti awọn alawọ funfun ko ilẹ Afrika ni ẹru, amọ o ṣeni laanu wi pe titi di ọdun 2020 ti a wa ninu rẹ lọwọlọwọ yii, bi kii ba ṣe lati idile ẹru, awọn idile ẹru naa ko le fẹ ọkọ tabi aya.
Bẹẹ ni ọrọ ri fun awọn ololufẹ meji to pa ara wọn ninu Oṣu Kẹsan an yii lẹyin ti awọn obi wọn kọ fun wọn lati fẹ ara wọn nitori ọkan ninu wọn wa lati idile ẹru ni ipinlẹ Anambra.
Iwe ikẹyin ti wọn kọ silẹ ni wipe 'A ko le fe ara wa nitori igbagbọ awọn baba nla wa'.
Awọn ololufẹ naa ti wọn ko ju ọmọ ọgbọn ọdun lọ wa lati ilu Okija ni ipinlẹ Anambra, nibi ti Ilẹ Gẹẹsi ti fofin de owo ẹru ni ọdun 1900s.
Bi o ba ti wqa lati iran ẹru ni ilẹ Igbo(Igboland), ko sọna fun ọ rara niyẹn o lati lọkọ tàbí ni aya.
Amọ, awọn ọmọ ti wọn wa lati ile ẹru ti wọn tu silẹ yii laaarin awọn ẹya Igbo ṣi n tẹle ohun ti awọn baba nla baba wọn ṣe ni igba aye wọn, eleyii to tumọ si wi pe ẹru ko le fẹ ọmọ laarin awọn ẹya Igbo.Awọn ololufẹ meji ti iru rẹ ti ṣẹlẹ si sọ wi pe o yẹ ki awọn ẹya Igbo yii mọ wi pe bi a ṣe bi ẹru la bi ọmọ, Olorun ko si fẹran ẹnikan ju omiran lọ, amọ aimoye ati igbagbọ ninu iṣẹṣe lo n mu ki awọn ẹbi ma a ṣe bi wọn ti n ṣe.
Arabinrin Favour ni ọkọ afẹsọna oun fi oun silẹ lẹyin ti awọn ẹbi rẹ sọ fun wi pe ko lee fẹ oun nitori idile ẹru ni oun ti wa.
Bakan naa ni wọn ja ọkọ afẹsọna oun laya titi ti o fi wa sọ fun oun wi pe ọkọ afẹsọna naa yoo ku ti o ba fẹ oun, nitori idile ẹru ni oun ti wa.
Ko tan sibẹ o, nitori kii se igbeyawo nikan ni wọn fi n dẹyẹsi awọn ti wọn ba wa lati idile ẹru ni ẹya Igbo,lorilẹede Naijiria.Ẹnikẹni to ba wa lati idile yii ko le e de ipo adari ni awujọ wọn, bakan naa ni ko le e dije -dupo , nitori ko si ẹni ti yoo dibo fun ẹni to wa lati idile ẹru.
Amọ, ko si ẹni to di wọn lọwọ lati ka iwe tabi jẹ olowo ati ọlọrọ ni awujọ.Eleyii mu ki ọpọlọpọ awọn to wa lati idile eru yii tete darapọ mọ ẹsin Kristẹni, nitori o waasu ominira fun wọn lasiko ti awọn ara wọn yoku ko Gbagbọ ninu rẹ.
Ideyẹsi ni nitori idile yii gbọdọ dopin - Oge MaduagwuNibayii, awọn ẹbi to wa lati idile ẹru yii wa lara awọn to ni ọrọ julọ ni agbegbe wọn, amọ ko si bi wọn ṣe le ṣe oriire to, awọn eniyan si ma n dẹyẹsi wọn gẹgẹ bi ẹni ti ko jamọ nkankan.Ni ọdun 2017, Arabinrin Oge Maduagwu gbe ajọ kan kalẹ ti yoo fi opin si idẹyẹsi ni ni agbegbe naa, eleyii ti o pe orukọ rẹ ni 'Eradication of Traditional and Cultural Stigmatisation in our Society (Ifetacsios).
'Lati bi ọdun mẹta naa ni o ti n kaakiri awọn ipinlẹ marun to wa ni iha Guusu orilẹede Naijiria lati ṣe idanilẹkọ tabi idẹyẹsi eniyan nitori wọn bi i si idile ẹru.
Maduagwu ni o ṣeni laanu wi pe iru iwa ẹlẹyamẹya ati idẹyẹsi si ni to n waye ni ilẹ Amẹrika naa n waye ni orilẹede Naijiria, ti oun si ṣẹtan lati fi ofin si iwa buruku yii.
Idile Ohu ati Osu ni idile ẹru ni Ile Igbo Awọn to wa lati idile ẹru yii pin si ọna meji- awọn kan wa ti wọn n jẹ Ohu ati Osu.
Awọn eniyan Ohu lo n fi awọn eniyan bi ti wọn ṣe owo ẹru, amọ awọn ara orun lo ni awọn ẹru ti wọn n pe ni Osu, ti wọn si ti fi wọn rubọ si awọn oriṣa.
Awọn idile Osu yii si ni idẹyẹsi wọn ma n pọju nitori orisa ti wọn ti fi awọn baba nla wọn rubọ si, ti wọn si n ṣe ẹru fun un.
Baba ọkọ afẹsọna Favour sọ fun wi pe ti o ba fẹ Favour, yoo tete ku , nitori idile Osu lo ti wa.'Iwe Chinua Achebe 'Things Fall Apart' fi agbara fun idẹyẹsi idile ẹru'- Bisọọbu Agba Ijọ AgudaBakan naa ni awọn iwe kika bii Iwe Chinua Achebe, 'Things Fall Apart' naa sọ itan bi Osu ṣe ri, ati iru igbeaye ti wọn ko le e gbe.
Ninu ero tirẹ, Bisọọbu Agba Ijọ Aguda ni ilu Imo, Anthony Obinna sọ wi pe opin gbọdọ de si idẹyẹsi ni yii ati ọrọ ẹlẹyamẹya nitori ọgbọgba ni Olorun da wa.
Bisọọbu Agba naa ni lọpọ igba ni oun ti ja fitafita fun awon ololufẹ to fẹ se igbeyawo, amọ ti awọn obi wọn ko fun won nitori ọkan lara wọn jẹ ẹru. O ni lọpọ igba ni wọn ti ma n dunkoko mọ oun nitori oun ma n ṣe igbeyawo fun awọn iru ololufẹ bayii.
' Fiimu Africa Magic n ṣe igbelaruge asa ati iṣe idẹyẹsini ni ilẹ Igbo'Arabinrin Maduagwu fikun wi pe o buru de ibi pe awọn eniyan ma n fi ẹya wọn pamọ nitori idẹyẹsi yii. Ati wipe o tilẹ ni awọn alarinna lati idile Osu ti orukọ wọn n jẹ Nneji, wọn ṣiṣẹ lati fopin si idẹyẹsi naa nipa mimu ololufẹ meji mọ ara wọn, awọn mejeeji yoo wa lati idile ẹru, ki wọn baa le fẹ ara wọn lai si ipọnju lati ọdọ awọn obi.
Bakan naa ni arabinrin Maduagwu fikun wi pe fiimu African Magic naa n fi agbara fun iwa ẹlẹyamẹya, nitori wọn n ṣe fiimu to n ṣe igbelarugẹ aṣa ati iṣe abalaye ni awọn agbegbe wọnyii.
Bi o tilẹ ṣe pe idẹyẹsi ati ẹlẹyamẹya yii ko wọpọ ni awọn ẹya miran ni orilẹede Naijiria bii Yoruba ati Hausa, awọn orilẹede miran ni Iwọ-oorun Ilẹ Afrika bii Mali ati Senegal naa ṣi n dẹyẹ si awọn eniyan nitori wọn wa lati idile ẹru.
Nitori naa awọn adari ni Ilẹ Afrika gbọdọ ṣe ayẹwo awọn nkan wọnyii finifini, ki wọn fi opin si iwa ẹlẹyamẹya ati idẹyẹsi ni laarin awujọ wọn.