You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan ti dero atimọle lẹyin ti ẹrọ ayaworan CCTV tu aṣiri rẹ lẹyin to fi ipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mọkanla lopọ.̣
Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Sapele, ni ipinlẹ Delta ninu ile kan ti wọn ri ẹrọ CCTV ọhun si.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Jomaph sẹ́, aworan CCTV ọhun fi han pe o wọ iyẹwu tọ ọmọdebinrin naa lọ.
- Toyin Abraham pé 40, wo ohun márùn ún tó mú dá yàtọ̀ láàrín ogójì ọdún
- Bí mo bá wọlé padà, mí ò lè yàn Ize Iyamu tàbí Osagiobare sípò olùbádámọ́ràn- Obaseki
- Facebook mú àyípadà bá àtẹ̀jíṣẹ́ síra ẹni lórí òpó Instagram, wo àwọn ǹkan tó kàn ọ níbẹ̀
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Kano tí ṣe àyẹ̀wò àwọn 13, 048 tó fẹ́ darapọ̀ mọ́ wọn
- Owó oúnjẹ ni mo lọ ọ gbà, oyún ọmọ tí mo jù sí àkìtàn ni mó gbé wálé- Dupe, ìyá Muiz
Iroyin ni, ni kete ti afurasi ọhun ri ara rẹ lori CCTV naa, ni ṣe lo yi ohun pada to si bẹrẹ si n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ki awọn agbofinro to wa fi panpẹ ofin mu un.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa, DSP Onome Onowakpoyeya sọ pe ṣaaju ni afurasi naa ti kọkọ sẹ pe ohun ko mọ ohunkohunn nipa ẹsun naa, ṣugbọn o jẹwọ lẹyin to foju gan ni aworan ara rẹ lori CCTV.
Onome ni "Inu ile igbọnsẹ ni ọmọdebirin naa wa ki afurasi ọhun to wọle tọ ọ lọ, ṣugbọn o sẹ pe ohun ko fọwọ kan an.
"koda o ni ṣe ni o fẹ ba oun lorukọ jẹ, ṣugbọn lẹyinorẹyin, o jẹwọ lẹyin ti o ri ara rẹ ninu CCTV.
"Onome pari ọro rẹ pe wọn ti bẹrẹ igbesẹ lati dari ẹjọ naa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwa ọdaran, CID.
- Wo àwọn òfin tuntun tíjọba fí síta lórí lílọ ìrìnàjò sílẹ̀ òkèèrè
- Wo ohun tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n ṣe fún Sunday Shodipe, afurasí ìṣekúpani l'Akinyele
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ìwọ́de l'Osogbo lórí àfikún owó epo bẹntiróò
- Èèmọ̀! Ọmọbìnrin ọdún 25 gún ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa nítorí ó ní ko lọ ṣẹ́ oyún
- Èsì ìdánwò òhun tí a ṣé síwájú là n bá fínra báyìí ní Nàìjíríà- Yemi Shodimu