Coronavirus: Wo ilé ìwòsàn kan ti tọmọ-tìyà ti ń kú lẹ̀yìn tí Covid-19 búrẹ́kẹ

Iwadii ikọkọ ileeṣẹ BBC ti tu aṣiri awọn ile iwosan kan ni South Africa nipa ohun toju awọn dokita ati nọọsi n ri lati ṣetọju awọn alaarun Coronavirus.

Awọn oṣiṣẹ kan kan daṣẹ silẹ, bẹẹ lawọn mii ti lugbadi arun naa iha ila-oorun Cape Town, ko da, awọn nọọsi kan funra wọn lo n gbalẹ, awọn to n ṣiṣẹ abẹ lo n fọ aṣọ ti wọn n wọ, bẹẹ la tun gbọ iroyin pe ọpọ awọn alaboyun kun ẹka ti wọn ti n bimọ ti ko si si ẹni ti yoo da si wọn.

Bi awọn dokita ṣe n tiraka lati lo awọn irinṣẹ ti ko to lati gba ẹmi awọn eeyan la lọwọ iku, wọn ti bu ẹnu atẹ lu ijọba fun iṣẹ ajanbaku to ṣe si ẹka eto ilera ilẹ ọhun.

Aarẹ ilẹ naa, Cyril Ramaphosa ti wa kede pe ọrọ arun Covid-19 kii ṣe ohun ti ijọba ilẹ naa lee fi ọwọ yẹpẹrẹ mu, o si ti pe e ni iji lile.

Ọkan lara awọn dokita to n ṣiṣẹ ni Port Elizabeth, John Black sọ pe ṣaaju arun Covid-19 ni awọn oṣiṣẹ wọn ko ti to n kan, arun naa si tun mu ki nnkan buru sii.

O ni "Ootọ ni pe a ko ni awọn oṣiṣẹ to to niye tẹlẹ, ṣugbọn lẹyin ti Coronavirus bẹrẹ, awọn oṣisẹ wa tun din sii pẹlu ida ọgbọn.

Dokita Black tẹsiwaju pe "Gbogbo nnkan ti bẹrẹ si n dojuru," lẹyin naa lo fidi rẹ mulẹ fun BBC pe awọn alaisan ma n ja si ẹrọ to n ran eemi lọwọ nile iwosan Livingstone to wa ni Port Elizabeth.

Black yii nikan lo ba BBC sọrọ, bo tilẹ jẹ pe wọn dokita ati nọọsi miran ba BBC sọrọ, ṣugbọn wọn ni ki a ma fi orukọ wọn lede nitori ibẹru pe iṣẹ lee bọ lọwọ wọn.

Ile iwosan di ile ekute

Awọn dokita ati nọọsi to n ṣiṣẹ nile iwosan Port Elizbeth sọ pe ile iwosan naa dabi eyi to wa loju ogun ni, nitori ẹjẹ ma n wa nilẹ kaakiri, bẹẹ lawọn eku maa n sare kiri nile iwosan naa.

Akọroyin ileeṣẹ BBC to yọju si ile iwosan ọhun ri awọn eku to n jẹun kiri nibi ti wọn da idọti si.

Ọkan lara awọn dokita ọhun to fi iwe ranṣẹ si BBC ni iṣẹ abẹ to ba ṣe koko julọ ni wọn ma n dojukọ nitori pe awọn oṣiṣẹ ko to.

Nọọsi mii tun sọ pe pẹlu ibẹrubojo ni oun fi n lọ si ibi iṣẹ lojojumọ.

Iya ati ọmọ n ku

Ibanujẹ ti dori awọn dokita kan kodo lẹyin ti wọn ri bi awọn obinirin ati ọmọ wọn ṣe dagbere faye laipẹ yii latari bi wọn ko ṣe ri oṣiṣẹ ti yoo ṣetọju wọn nitori pe awọn alaisan pọ ju olutọju lọ nile iwosan Dora Nginza ni Port Elizbeth.

Wọn ni awọn iku ọhun ki ba mati waye, ṣugbọn ko si awọn ti yoo ṣetọju awọn ọhun ni, fun apẹrẹ, alaboyun to nilo iṣẹ abẹ.

Ọkan lara wọn tilẹ sọ pe arun Covid-19 to de lo fun wọn ni anfani lati lee sọ ohun ti oju wọn n ri lẹnu iṣẹ ọhun.

Pẹlu bi gbogbo nnkan wọnyi ṣe n ṣẹlẹ, awọn nọọsi ati dokita naa tun n gunle iyanṣẹlodi.

'A ko lee fi ẹmi awọn nọọsi wewu'

Awọn aṣoju ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti sọ pe ko si ohun to buru ti wọn ba daṣẹ silẹ.

Akọwe agbegbe fun ẹgbẹ awọn nọọsi nilẹ naa, Khaya Sodidi, sọ pe "A ko le fi ẹmi awọn nọọsi sinu ewu nitori awọn oṣiṣẹ to n gbalẹ nile iwosan ti daṣẹ silẹ."

"Awọn nọọsi funra wọn lo n gbalẹ bayii, eeyan lawọn naa, a ko si lee fi ẹmi wọn wewu."

Ẹwẹ, nigba to n sọrọ lori awọn ohun ti oṣiṣẹ eto ilera sọ, akọwe agba ileeṣẹ to n ri si eto ilera ni iha ila-oorun Cape Town, Thobile Mbengashe sọ pe ootọ ni.

O ni ọpọ ninu awọn dokita ati nọọsi naa ni ẹru n ba lati ṣe ojuṣe wọn lẹnu iṣẹ.

Ṣugbọn o fi kun pe awọn ile iwosan to wa labẹ rẹ n ṣe ojuṣe wọn.