Cameroon first daughter: Ọmọ ààrẹ lọ ṣí sọ́ọ́bù irun ṣí Amerika

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oriṣiriṣi awuyewuye àti ariwisi lo ti n waye lori bi Brenda Biya, ọmọ aarẹ orilẹ-ede Cameroon, Paul Biya ṣe ṣi sọọbu irun tita silẹ Amerika.

Ana ni àkọ́bí aarẹ ṣi ile itaja náà silu Los Angeles, to si sọ pe nkan akọkọ ti oun ṣe àṣeyọrí sí rere lori rẹ ni yẹn.

Ninu ikede to fi sita lori ayelujara Twitter, Brenda sọ pe sọọbu naa tobi pupọ, ati pe o wa fun awọn obinrin to ba fẹ ẹ ṣe irun wọn ni ọsọ tàbí ra wiigi ti wọn fi 'irun eniyan' ṣe.

Sugbọn sebi Yoruba sọ pe oun to kọjú si ẹnikan, ẹyin lo kọ sí ẹlòmíràn. Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun ọmọ aarẹ Biya, nitori pe bi awọn kan ṣe n ki kú oriire, ni awọn miran n bu ẹnu ẹtẹ lu u pe ko tọ ọ bo ṣe ṣi sọọbu irun si Amẹrika.

Wọn ni orilẹ-ede Cameroon lo yẹ ko ṣi i si, lati le pese isẹ fun awọn araalu.

Awọn miran ti ẹ sọ pe owó orí ti awọn araalu n san lo fi lọ ọ ṣi ile itaja si orilẹ-ede miran.

Ọdun mejidinlogoji re e ti Aarẹ Biya ti wa nipo, àwọn kan si n sọ pe ọmọ rẹ, Brenda n tun ọjọ iwajuu ara a rẹ ṣe ni, torí ti baba rẹ ba fi ipo silẹ.