Awọn akanda ti fẹhọnu han tako ijọba Eko lori fifi ofin de maruwa ati ọkada.

Àkọlé fídíò, Awọn akanda ti fẹhọnu han tako ijọba Eko lori fifi ofin de maruwa ati ọkada.

Awọn akanda eniyan ni ipinlẹ Eko ti bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ijọba to tako lilo maruwa ati ọkada fi ṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa.

Awọn akanda naa fi ero wọn han lasiko ti wọn ṣe iwọde ni ipinlẹ naa ni Ọjọ Ẹti.

Awọn ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ lara wọn sọ wi pe ijọba ipinlẹ Eko sọ wi pe ki awọn ye e tọrọ owo mọ, awọn si gbọ si wọn lẹnu, amọ wọn fi ẹsun kan wọn bayii wi pe wọn ti gba ijẹ lẹnu wọn.

Wọn fi kun wi pe ijọba Eko ko saanu wọn nitori wọn ko ro bi awọn yoo ṣẹ jẹun tabi bọ ara ati ẹbi awọn bayii.

Awọn akanda naa wa rọ ijọba lati tun ero wọn pa nitori wiwa maruwa ati ọkada ni awọn fi n jẹun.