Elegible Bachelors: Àwọn àpọ́n olówó Marun tí kò tíì laya

Lẹ́yìn ti ọdọ́kunrin ba ti kàwé tan to si ni iṣk ti o dára lọ́wọ́ àdura to ku náà ni pe ki o lọ mú òdòdó to bá ń wá láti ti fi ṣe aya.

Kò si àniani, ìyì ńla ni ti ọkùnrin ba lówó lọ́wọ́ to si tún rẹwàá gbogbo ọmọge ni yóò ma yọwọ́ ọṣẹ pe bí èyi kò ba tilẹ̀ jẹ́ ọkọ ẹni, o yẹ ki o le jẹ́ àlè ẹni.

Ẹ̀wẹ̀ àwọn ọkùnrin Marun-un rèé lórìlẹ èdè Naijiria, ti wọ́n rẹwà, ti wọ́n lówó lọ́wọ́ ti wọ́ sì tún ti ilé ire jáde wa, sùgbọ́n ko ti si obìnrin ní ẹ̀ẹ̀dẹ wọ́n kò si ẹni to ye ìdí ti wọ́n ko se ti mu aya.

Ọdọkùnrin àpọn Marun ti kò ti láya

Jide Adenuga

Jíde ni àkọbi ọmọ gbajúgbajà onísòwò ń ni Mike Adenuga, ọpọ nibi gbogbo lo n jẹ ọrọ ìgbéyàwo Jide lẹ́nu nibi gbogbo, ọkùnrin rọ̀gbọ̀dọ, to dùn wò to tun ní ìmọ to pọ nipa òwò 'siṣe.

O ti fi ìgbà kan ṣe adari ile ifowopamọ kan ri to si tun n dari ile iṣẹ́ mẹta miran.

Bótill jẹ́ pe ìdile to ti jáde kìí fi bẹẹ gbé ara rẹ han si ori afẹfẹ, ọpọ ni ko mọ ǹkankan nipa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ Jide, sùgbọ́n o ti didandan ìgbà kùùgba ti o ba ṣetan, awo damiẹnu ni àyẹyẹ ìgbéyawó rẹ̀ yóò jẹ.

Sijibomi Ogundele

Sijibomi Ogundele ni alasẹ ati oludari ile iṣk tirẹ náà Sijimoto, o ni pe ìràn òn ni iru ti Trumps àti Candy Brothers nínú ka ta ile ka ra ilẹ̀, o si jọ bi ẹni pe ọlorun gba ìràn náà fun.

Ní ti Siji o ni kò yé ọkùnrin wà lai ni aya, ati pe òun yóò gbiyanju la'ti ni aya.

Gẹ́gk bi o ṣe sọ o ni agaogo ìgbéyawo yóò dùn níle oun nínú ọdun yii.

Nínú ìpínnu ọdun rẹ ni ọdun yìí lori àtẹjiṣe Instagram rẹ "Mo ṣetan lái ṣe igbéyawo nitori òun ni gbogbo ǹkan fun mi"

Paddy Adenuga

Ọkan lára àwọn apọn ni Paddy ti bi sínú ọlá to si tun ni òye owò síṣe, Omo Mike Adenuga ni pẹlú,sùgbọ́n o wá ààye ọtọ fú ara rẹ̀.

Paddy ya iṣẹ́ tirẹ sọtọ si ti baba rẹ ti o si dfim olú ile iṣẹ́ tireẹ̀ si òkè okùn

Bótilẹ̀ jẹ́ pe èèmeji ọtọọtọ ni Paddy ti gbe sori ayelujara pé oun ti ni ololufẹ síbẹ̀ ko si èyi to yọri. "Moti ṣe alabarin obinrin ni èèmeji,sùgbọ́n ko si èyi to yọri"

Mi o le fa ọwọ ọlọrun ni dandan, àsìkò rẹ ni mo n reti, 'Ni bayi bi oju ọjọ ba ṣe ri ni mo se n tọ

Sùgbọ́n ṣe ki a maa parọ ọmọkunrin náà buyi púpọ.

Ladi Delano

Orúkọ yìí le ma hàn si gbogbo ènìyàn amọ ṣe ẹ fẹ gbọ òun ni wọ́n n pe ni o jẹ ǹkan rìgìdì ṣẹnu káló, Ladi kọkọ ka miliọnu rẹ nigbà ti o wà ni ọmọ ọdun mérinlelógun.

Ẹni to ba ti ṣe alábapade Delano yóò ma pe àwọn ni wọ́n sọ si Naijiria to ni ninu ọmọde olówó< kìí ṣe alariwo ẹda sùgbọ́n o mọ ọ̀na ti a gba ri owó.

Gbájugbaja ninu ki a kó ẹlẹrindodo wọ orilẹ-èdè Naijiria.

Botilẹ jẹ pe jẹjẹ ni ọmọ Eko n lọ ni Ladi, sùgbọ́n sibẹ o jẹ ọkan lára àwọn ọkunrin ti àwọn obinrin ń sá tèlé ní Naijiria toni

Adebola Williams

O dára ju láti sàkàwe Addebola orẹ gbogbo ẹni to ṣe pàtaki ni orilẹ̀-èdè Naijiria, ọdọmọde onísòwò náà máà saba foju han lori ayelujara nítori bo ṣe maa n nawọ ìràwọ si àwọn ọrẹ rẹ̀.

Williams jẹ alajodasilẹ Red Africa to jẹ ọkan to tobi fun agbejade awon ọdọ ni Afrika

O jẹ ọkan lára àwọn to ṣeto agbéjade ààrẹ Buhari lọdun 2015, bakan náà lo ṣiṣẹ pọ pẹlu à[rẹ Orilẹ̀-èdè Ghana Nana Akufo -Ado la'siko idibo rẹ̀ lọdun 2016.

ọ̀pọ̀ lo ti n bi ẹni ọdun mẹtalelọgbọ̀n òun pe ìgbàwo ni yóò mu aya wále.