You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FIFA Football Awards: Messi la Ronaldo, Van Dijk láti gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ lágbayé
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé wọn ti kede Lionel Messi gẹgẹ bii agbabọọlu FIFA to pegede julọ lagbaye.
Messi to jẹ balogun ikọ orilẹede Argentina ati Barcelona n gba ami ẹyẹ naa fun igba kẹfa.
Messi, Ronaldo ati Van Dijk ni awọn agbabọọẹu mẹta ti wọn yan fun ami ẹyẹ yii.
Saaju ikede agbabọọlu to ku oju iwọn julọ lagbaye ni wọn ti kede olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ni wọn yan gẹgẹ bii olukọni to pegede julọ.
Awọn ami ẹyẹ miran ti wọn kede ni iwọnyii:
Aṣọle to pegede julọ lagbaye-
1.Allison Becker
Awọn balogun adilemu to pegede julọ:
1.Matthijs de Ligt
2.Sergio Ramos
3.Van Dijk
4.Marcelo
Awọn agbablu aarin to pegede
1.Luca Modric
2.Frenkie de Jong
3.Eden hazard
Agbawaju to pegede:
1.Kylian Mbappé
2.Lionel Messi