You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Security Tracker: Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria ti kú sí rògbòdìyàn ó n ṣẹlẹ̀
Iwadii ajọ orilẹ-ede Amerika kan ló fidi ẹ mulẹ pé ọpọ ẹ̀mí ti sọnu ni Naijiria.
Iwadii naa ni awọn to ku ninu oriṣiriṣi rogbodiyan ni orilẹ-ede yii ni lati ọdun mẹrin sẹyin din diẹ ni ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn.
Iwadii naa to da lori iṣẹ ẹka ajọ lori ọ̀rọ̀ aabo ni Naijiria (Nigeria Security Tracker) ni awọn wọnyii ni Boko Haram ati awọn daradaran pa pẹlu awọn ti ikọ ologun Naijiria pa laitọ nigba ti wọn n koju igbesunmọmi.
Laarin oṣu kẹfa, ọdun 2015 si oṣu karun un, ọdun 2019 ni wọn fi ṣe afojusun iṣẹ iwadii naa.
Ipinlẹ Borno lo ko eyi to ju ninu awọn iku wọn yii nibi ti ẹ̀mí eniyan to ju ẹgbẹrun mẹsan an (9,303) ti lọ, Zamfara (1,963) ati Adamawa (1,529) lo tẹ lee.
Ipinlẹ Jigawa lo ni iku to kere ju pẹlu eniyan meje. Ipinlẹ Eko gan an ni ju ọọdunrun eniyan lọ (337).
Iwadii naa ni laarin ọdun mẹta yii, ni awọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram ti pa eniyan 5,598, ti ija awọn daradaran si pa eniyan to din diẹ ni ẹgbẹrun marun un (4,917).
Atẹjade ajọ naa ni awọn agbofinro naa pa ju ẹgbẹrun mẹrin eniyan lọ (4,068) laarin ọdun mẹrin yii,